Gomina AbdulRazaq gba awọn ọba naa lamọran lati lo ipo wọn fi mu ki iṣọkan, ifẹ ati alaafia jọba laaarin awọn ilu ti wọn yoo bẹrẹ sii ṣakoso rẹ, fun idagbasoke ati itẹsiwaju.
Ọjọbọ tii ṣe Tọside, ọsẹ to ṣẹṣẹ pari yii ni gomina gbe ọpa ati iwe aṣẹ naa le Ọba Isiaka Malik lọwọ gẹgẹ bii Alagunjin tiluu Agunjin.
Bakan naa ni Ọba AbdulRazaq Adekola Salau gẹgẹ bi Olowo tiluu Ita-Olowo, ati Ọba Afolabi Odeniyi Gabriel gẹgẹ bii Elepe tiluu Epe-Opin.
Ipele kẹta ni Alagunjin nijọba ibilẹ Ifelodun wa ni ipele awọn ọba, nigba ti Olowo nijọba ibilẹ Ifelodun ati Elepe tijọba ibilẹ Ekiti wa ni ipele kẹrin.
Nigba to n sọrọ, Gomina AbdulRazaq ti Kọmiṣanna fọrọ eto ijọba ibilẹ, oye jijẹ ati idagbasoke agbegbe, Ọnarebu Abubakar Abdullahi Bata ṣoju fun, sọ pe ipo ẹlẹgẹ ni ipo ọba, ti wọn si gbọdọ lo o lọna to tọ.
"Mo ki ẹyin ọba tuntun ati awọn ilu yin ku oriire yii. Mo gbadura pe ki ipo yin mu ọgbọn, alaafia ati itẹsiwaju wa,” Kọmiṣanna sọ bẹẹ.
O ni ki wọn tubọ maa fi arajin fun iṣẹ isinlu, paapaa si awọn to gbaruku ti bi ipo naa ṣe ja mọ wọn lọwọ.
Lara awọn to wa nibẹ ni Ọnarebu Ganiyu Gabriel; alaga ijọba ibilẹ Ifelodun, Ọnarebu Femi Yusuf; Ọnarebu Awelewa Olawale Gabriel; alaga ẹgbẹ oṣelu APC, Ọmọọba Sunday Fagbemi; to fi mọ awọn mọlẹbi, oloye ati afẹnufẹrẹ.
No comments:
Post a Comment