Ile ẹjọ Majisireeti to wa niluu Akurẹ, ipinlẹ Ondo ti sọ pe ki Tọpẹ Ademẹṣọ ati Igbẹkẹle Akinsioye ṣi lọ maa gbatẹgun lọgba ẹwọn lori ẹsun ifipabanilopọ.
Ọmọdebinrin, ọmọ ọdun mẹtadinlogun la gbọ pe awọn mejeeji fipa gba aṣọ iyi lara rẹ, lai bikita atubọtan.
Awọn mejeeji la gbọ pe wọn ko niṣẹ meji ju iṣẹ ọkada wiwa lọ, ti wọn gbajumọ daadaa nigboro ilu Akurẹ.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọwọ ẹṣọ aabo Amọtẹkun lo tẹ Tọpẹ ati Igbẹkẹle lagbegbe Continental.
Nnkaj bi agogo mẹwaa aarọ ọjọ kẹfa, oṣu Kẹjọ, ọdun yii ni wọn sọ pe awọn mejeeji naa fipa ba ọmọ naa laṣepọ.
Ẹsun meji ọtọọtọ ni ẹṣọ aabo Amọtẹkun fi kan wọn, eyi to nii ṣe pẹlu igbimọ papọ ati ifipabanilopọ.
Ẹsun naa ni awọn agbefọba sọ pe o tako owe ofin ọdaran tipinlẹ Ondo tọdun ni abala 516, to si ni ijiya ninu.
Bo tilẹ jẹ pe awọn mejeeji sọ fun adajọ wi pe awọn ko jẹbi, sibẹ, Onidajọ Damilọla Ṣekoni paṣẹ pe ko awọn mejeeji wa lọgba ẹwọn titi ti igbẹjọ miran yoo fi waye lọjọ kinni, oṣu Kẹsan, ọdun yii.
No comments:
Post a Comment