Wọn dajọ iku fun ọlọpaa ati ayedero ṣọja l’Akurẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, August 17, 2025

Wọn dajọ iku fun ọlọpaa ati ayedero ṣọja l’Akurẹ


Ile-ẹjọ giga tipinlẹ Ondo to wa niluu Akurẹ ti dajọ iku fun ọlọpaa kan, David Friday ati ọkunrin kan to n fi aṣọ ṣọja lu jibiti, Innocent Victor lori ẹsun idigunjale.

Ẹsun mẹrin ọtọọtọ to nii ṣe pẹlu igbimọ papọ, pipe ara ẹni ni lohun ti ko jẹ, idigunjale ati fifi iṣẹ ologun ati ọlọpaa lu jibiti, eyi to tako abala kẹfa ninu iwe ofin ilẹ Naijiria ti ọdun 2004 to nii ṣe pẹlu lilo ohun ija oloro.

Ọkan lara awọn ẹlẹrii ti agbefọba ranṣẹ pe, Akinmodun Akinleye, sọ fun ile-ẹjọ pe awọn meji naa da oun duro lasiko toun n bọ lati inu oko oun to wa lagbegbe Ojalade ni nnkan bi agogo kan oru, ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kinni, ọdun 2021.

Akinleye sọ pe ọkan lara wọn wọ aṣọ ọlọpaa dudu, nigba ti ẹnikeji wọ aṣọ ologun, to si lawọn mejeeji lo mu ọbẹ lọwọ.

O ni bi wọn ti ṣe ri oun lati ọọkan ni wọn ti n tan ina ọkada TVS soun, ko to di pe wọn da oun duro.

Ọkunrin naa ni wọn yẹ gbogbo inu ọkọ ayọkẹlẹ oun wo, wọn si ko ẹgbẹrun mẹfa naira nibẹ, wọn tun loun gbọdọ ra epo sinu ọkada awọn, ati pe nigba to ya loun rii pe wọn ti ji foonu iTel toun ra lẹgbẹrun mẹjọ aabọ.

Bakan naa ni ẹlẹrii miran, Olowogbadegun Lanre, to loun yan iṣẹ ọlọdẹ laayo lagbegbe ikorita Yaba niluu Idanre, sọ pe ni alẹ ọjọ naa, oun ri ọkunrin meji ti wọn wọ aṣọ ọlọpaa ati ṣọja. 

O sọ pe wọn wa ba oun, wọn si ni koun ju ibọn ọwọ oun silẹ, ṣugbọn to loun kọ jalẹ. O ni ko pẹ ti wọn tun da ọkọ bọọsi akero elero mejidinlogun duro, ti wọn si wọ awakọ naa bọ silẹ, ko to di pe wọn gba gbogbo owo ọwọ rẹ.

Olowogbadegun sọ pe wọn lu awakọ naa lalubami, wọn si gba ẹgbẹrun marun-un naira lọwọ rẹ. O ni wọn foun ni ẹgbẹrun meji naira, ṣugbọn to loun ko gba a.

Siwaju sii lo sọ pe nigba ti wọn lọ, awakọ bọọsi naa wa ba oun, toun si sọ pe oun da wọn mọ. O ni teṣan ọlọpaa lo gba lọ lati fi ẹjọ sun, leyi to jẹ ki ọwọ tẹ wọn.

Ko tan sibẹ, ẹlẹri kẹta naa, Adeyeye Sesan sọ pe awọn mejeeji yii da oun duro lalẹ ọjọ naa, wọn si n beere ẹgbẹrun mẹwaa naira lọwọ oun, o nigba toun  ko fun wọn, lo jẹ ki wọn lu oun lalubami, ko to di pe wọn ji ẹgbẹrun marundinlaadoje naira lọwọ oun salọ.

Lẹyin eyi lo sọ pe wọn ṣe oun leṣe ni ẹsẹ, ti wọn si dunkooko lati pa oun danu.

Agbefọba Ilasanmi Samuel wa sọ fun ile-ẹjọ pe iwadii fidi rẹ mulẹ pe ọlọpaa to n ṣiṣẹ lagọ ọlọpaa ti ẹkun Olofin, niluu Idanre ni David Friday, nigba ti Innocent Victor jẹ ayederu oṣiṣẹ ologun.

Onidajọ W.R. Olamide to gbọ ẹjọ naa sọ pe awọn ẹri toun ri gba fidi otitọ mulẹ, ati pe ẹlẹṣẹ kan ki yoo lọ lai jiya, to si paṣẹ pe ki wọn lọ yẹgi fun awọn mejeeji, nitori pe wọn ko yẹ lati maa gbe lawujọ awọn eniyan mọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI