Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ elepo rọbii lorileede Naijiria, iyẹn Nigeria Union of Petroleum and Natural Gas Workers, NUPENG ti kede sita pe awọn ti so iyanṣẹlodi wọn rọm
NUPENG jẹ ko di mimọ pe awọn gbe igbesẹ naa lẹyin ajọsọ ati adehun ti wọn ṣe pẹlu ileeṣẹ elepo Dangote, iyẹn Dangote Refinery and Petrochemicals lori ọrọ to nii ṣe pẹlu ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ wọn.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee to kọja ni NUPENG sọ pe awọn ṣepade pẹlu awọn alakoso ileeṣẹ Dangote naa, ti awọn si fẹnu ko lori adehun.
Ọpọ ileepo kaakiri ilẹ Naijiria ni wọn ti pa lọjọ Iṣẹgun, lẹyin ti NUPENG kede iyanṣẹlodi ọlọjọ meji.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ko sohun meji to fa iyanṣẹlodi naa, bi ko ṣe ẹsun ti wọn fi kan ileeṣẹ Dangote wi pe wọn ko fẹ ki awọn oṣiṣẹ wọn darapọ mọ ẹgbẹ oṣiṣẹ to yẹ lori aabo iṣẹ wọn.
Nibi ipade to waye laaarin minisita f'ọrọ epo rọbii lorileede Naijiria, Muhammad Maigari Dingyadi, ati awọn tọrọ naa kan, ni wọn ti jọ tọwọ bowe adehun to yẹ niluu Abuja.
Iwe adehun naa sọ pe “Niwọn igba to jẹ pe ẹgbẹ ṣiṣe jẹ ẹtọ ni ibamu pẹlu ofin to de e, ileeṣẹ elepo rọbii Dangote ati awọn oṣiṣẹ wọn ti gba lati ṣe ẹgbẹ.
“Wi pe igbesẹ lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣiṣẹ yoo bẹrẹ loju ẹsẹ, ti wọn si gbọdọ pari laaarin ọsẹ meji (ọjọ kẹsan si ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹsan, ọdun 2025), ati pe wọn fẹnu ko pe ileeṣẹ naa ko nii da ẹgbẹ miran silẹ.
“Lori awọn koko to jẹyọ nipa iyanṣẹlodi naa, ko si oṣiṣẹ ileeṣẹ elepo rọbii Dangote ti wọn gbọdọ dunkooko mọ.”
No comments:
Post a Comment