Ijọba ipinlẹ Kwara ti kede owo ti ko din ni miliọnu mẹjọ ataabọ naira gẹgẹ bi owo ti awọn ẹlẹsin Isilaamu yoo fi rin irin ajo lọ silẹ mimọ Hajj fun ọdun 2026.
Ileeṣẹ to n ri sọrọ eto irin ajo Hajj nipinlẹ naa, Kwara State Muslim Pilgrims Welfare Board lo fi iroyin ọhun lede lọjọ Aje, ọsẹ yii.
Wọn ni eto ti bẹrẹ fun awọn arinrin-ajo lati gba fọọmu ti wọn yoo fi rin irin ajo naa
Akọwe agba ileeṣẹ naa, Alaaji AbdulSalam Abdulkadir fidi iroyin naa mulẹ lasiko to n dahun ibeere lati ọdọ awọn akọroyin niluu Ilorin, ipinlẹ Kwara.
Alaaji Abdulkadir ṣalaye pe miliọnu mẹjọ ataabọ naira ni owo ti ajọ to n ri sọrọ eto irin ajo Hajj lorileede Naijiria, National Hajj Commission of Nigeria (NAHCON) buwọ lu fawọn arinrin-ajo lati san.
O ni arinrin-ajo to din diẹ ni ẹgbẹrun mẹrin (3,762) ni ajọ naa buwọ lu fun ipinlẹ Kwara.
Bakan naa lo ṣalaye lẹkunrẹrẹ nipa ilana ti awọn arinrin-ajo naa yoo tọ lati ṣe iforukọsilẹ ati gbedeke ọjọ ti iforukọsilẹ yoo dopin.
Bẹẹ lo dupe lọwọ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq fun ọna to n gba lati mu irọrun ba awọn arinrin-ajo naa nilẹ Saudi titi digba ti wọn yoo pada sile.
No comments:
Post a Comment