Awọn akẹkọọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ titi de girama kaakiri ipinlẹ naa ni ijọba sọ pe wọn yoo bẹrẹ ikẹkọọ saa tuntun naa.
Ọjọru, Wẹside, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹsan, ọdun 2025 ni ijọba gbe ikede naa sita, lati jẹ ki gbogbo awọn tọrọ kan maa gbaradi.
Kọmiṣanna f'ọrọ eto ẹkọ nipinlẹ Kwara, Ọmọwe Lawal Olohungbebe nigba to n fidi rẹ mulẹ, o ni gbogbo eto lo ti to patapata fun awọn akẹkọọ ati olukọ lati bẹrẹ saa tuntun to fẹẹ bẹrẹ.
Ọmọwe Olohungbebe ṣalaye pe eto aabo ati ayika to dara fun eto ẹkọ ni wọn ti ṣagbekalẹ rẹ.
Olohungbebe ni awọn ti fẹnu ko nibi ipade awọn alẹnulọrọ lẹka eto ẹkọ nipinlẹ naa, lati ṣagbeyẹwo igbaradi fun ikẹkọọ saa tuntun.
Kọmiṣanna sọ pe atilẹyin Gomina AbdulRahman AbdulRazaq fun ẹka eto ẹkọ naa n so eso rere, to fi mọ ọrọ igbayegbadun akẹkọọ ati olukọ.
O wa rọ awọn obi ati alagbatọ, to fi mọ awọn tọrọ kan lati tubọ maa ṣagbatẹru ijọba lori ilọsiwaju ati ayipada rere to n de ba eto ẹkọ nipinlẹ Kwara.
No comments:
Post a Comment