Ileeṣẹ ifọpo Dangote ti jẹ ko di mimọ pe afaimọ ni ki ọwọngogo ma tun pada ṣẹlẹ ni Naijiria bi awọn alagbata epo ba fi tẹle aṣẹ ajọ to n ri sọrọ epo rọbii ati afẹfẹ gaasi ni Naijiria, iyẹn Petroleum and Natural Gas Senior Staff Association of Nigeria (PENGASSAN) gbe kalẹ laipẹ yii
Awọn alakoso ileeṣẹ Dangote sọ pe bi awọn eeyan ba tẹle aṣẹ naa, yoo fa ọwọngogo, aisi epo, akoba fun eto ọrọ aje ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Wọn ni bi wọn ba fi le mu ẹdinku ba bi wọn ṣe n gbe epo rọbii, iyẹn Crude Oil ati afẹfẹ gaasi jade, yoo jẹ k'awọn araalu tun bẹrẹ sii to lati ra epo lawọn ileepo lorileede Naijiria.
Ninu atẹjade ti awọn alakoso ileeṣẹ Dangote fi sita lopin ọsẹ to kọja yii, wọn ṣapejuwe aṣẹ naa gẹgẹ bi “iwa ọdaran, ainironu, ati erongba lati dabaru eto ọrọ aje.”
Dangote sọ pe bi wọn ba fi tẹle aṣẹ naa, yoo tun jẹ ki epo bẹntiroolu, disuu, epo ọkọ baluu, kerosiini ati afẹfẹ gaasi idana di ọwọngogo laarin ilu.
Wọn ni awọn nnkan wọnyi ni lilo wọn ṣe pataki si igbe aye ẹda lojooju, ati pe wọn jẹ ijiya ainidi fawọn ọmọ Naijiria.
"Ẹri wo ni ajọ PENGASSAN fẹẹ fi lelẹ lati tun dabaru, ki wọn si tun ṣagbekalẹ iya ainidi fawọn ọmọ Naijiria? Taa ni ajọ PENGASSAN n gbe lẹyin rẹ lati jẹ ki awọn araalu tun koju iṣoro ọwọngogo? Kii ṣe nipa ifẹ ọmọ Naijiria ni wọn fi n gbero lati ṣagbekalẹ iwa ọdaran bẹẹ, lati pọn araalu loju."
Siwaju sii ni wọn ṣe ikilọ pe wọn fẹẹ doju eto ọrọ aje ijọba bolẹ, pẹlu bo ṣe jẹ pe ileeṣẹ to n san owo ori to pọ ju ni ipinlẹ ati ijọba apapọ ni wọn n tako.
Wọn ni bi idaduro ba ṣẹlẹ, yoo da owo to n wọle sapo ijọba naa duro ni, leyi ti ko yẹ ko ri bẹẹ.
No comments:
Post a Comment