A ko tii gba ominira, ayafi bi awọn ọmọ Naijiria ba... - Oluwo sọrọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, October 1, 2025

A ko tii gba ominira, ayafi bi awọn ọmọ Naijiria ba... - Oluwo sọrọ


Oluwo tiluu Iwo, Ọba AbdulRosheed Adewale Akanbi ti sọ pe oun fi ọjọ ayajọ ominira ilẹ Naijiria jin fun gbogbo awọn ti wọn padanu ẹmi wọn nipa fifi wọn ṣẹṣo owo.

Ọba Akanbi, Telu kinni lo sọ bẹẹ ninu ọrọ rẹ fun ti ayajọ ọjọ ominira ti ọdun 2025.

Lonii, ọjọ Kinni, oṣu Kẹwaa, ọdun 2025 ni orileede Naijiria n ṣajọyọ ayẹyẹ ọdun marundinlaadọrin wọn gba ominira kuro lọwọ awọn ijọba amunisin, ti wọn si da duro gẹgẹ orileede.

Oluwo ninu ọrọ rẹ, sọ pe "Bi a ti n ṣajọyọ ayajọ ọjọ ominira, mo ba mọlẹbi ati awọn to ti padanu ẹmi wọn nipa fifi wọn ṣẹṣo owo kẹdun."

Ọba alaye naa sọ pe "Bi iṣẹlẹ pipani ṣẹṣo ọla ṣe pọ rẹpẹtẹ jẹ eyi to n kọni lominu. A ko tii dii ominira ayafi bi awọn ọmọ Naijiria ba ni alaafia kuro ninu iṣẹ ati oṣi ọkan, eyi to n fa pipa awọn alaiṣẹ lati fi ṣẹṣo owo 

"Ẹjẹ to wa lori ilẹ n beere, bẹẹ lo n banujẹ. Ijọba n gbiyanju lọpọlọpọ, ṣugbọn awọn mujẹmujẹ n ba gbogbo rẹ jẹ.

"Ijọba ni lati gba ilẹ yii silẹ nipa ṣiṣe agbekalẹ ofin ti yoo maa gbogun ti iwa ipani ṣẹṣo. Ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ wi pe o pa ẹda ẹgbẹ rẹ lati fi ṣẹṣo ni wọn ran lọ sibi toun naa ko fẹ 

"Bakan naa, iwa ka maa da awọn eeyan duro sile, lati ma ṣe rin bo ṣe wu wọn nitori etutu, gbọdọ jẹ ohun ti ijọba yoo maa yẹwo. Nini ominira gbọdọ tan de awọn aṣa ti ko ni ọlaju.

"Awon to n pa eeyan ṣẹṣo ko nii pari aye wọn daradara. Iran wọn yoo parun debi wi pe wọn ko nii kofiri wọn mọ. 

"Ayafi bi ijọba ba ṣe ohun to tọ, nko le sọ pe a ni ominira," Oluwo kadi ọrọ rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI