Ijọba ipinlẹ Ogun labẹ iṣakoso Gomina Dapọ Abiọdun ti jawe gbele ẹ fungba diẹ fun awọn ọga ile ẹkọ girama ti Ilugun, iyẹn Ilugun High School to wa niluu Abẹokuta.
Kọmiṣanna feto ẹkọ, Ọjọgbọn Abayọmi Arigbabu lo kede nirọlẹ ọjọ Iṣẹgun to kọja yii.
Arigbabu nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ ni ọfiisi rẹ to wa ni Oke Mọsan jẹ ko di mimọ pe awọn ọga ile ẹkọ girama naa ti tapa si ofin ilana eto ẹkọ nipinlẹ naa, ti wọn si gbọdọ foju winna ofin.
Arabinrin Olukọga Adeyẹmi Alaba to jẹ ọga ile ẹkọ kekere ati Arabinrin Ladipọ Ọlabisi Temitọpẹ toun jẹ ọga ile ẹkọ agba ni ile ẹkọ girama ti Ilugun lawọn mejeeji ọhun.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, laipẹ yii ni iroyin kan jade sita wi pe awọn akẹkọọ kan ku sodo Arakanga nibi ti awọn ẹṣọ aabo Amọtẹkun ti n le wọn, ti ọrọ naa si pada yiwọ.
Fọnran kan to gba ori ayelujara laaarọ ọjọ Iṣẹgun naa, eyi to tẹ GBELEGBỌ lọwọ la ti ri awọn akẹkọọ naa nibi ti wọn ti n fa wahala, ti wọn si n ba dukia ile ẹkọ naa jẹ.
Ninu fọnran ọhun ni wọn lawọn akẹkọọ naa ti n fẹhonu han lori iku awọn akẹgbẹ wọn ti ku iku aitọjọ, ti wọn si lawọn ko nii gba.
Ọjọgbọn Arigbabu nigba to n sọrọ lori fọnran naa sọ pe ohun ṣe pataki ni lati jawe jokoo sile fawọn ọga ile ẹkọ mejeeji naa, nitori ipa ti wọn ko lori rogbodiyan to ṣẹlẹ.
Kọmiṣanna naa ṣalaye pe iwadii ti awọn ṣe lori ohun to ṣẹlẹ pads jẹ ko di mimọ pe awọn mejeeji n gba owo ti ko tọ lọwọ awọn akẹkọọ, lẹyin ọpọlọpọ ikilọ ti ijọba ti ṣe lati dẹkun iwa ibajẹ nile ẹkọ.
O ni owo aitọ naa lo mu ki awọn akẹkọọ naa fẹhonu han, leyi to ṣokunfa iku ọmọ kan nibi ti awọn ẹṣọ aabo ti n gbiyanju lati da wọn lọwọ kọ.
“Gbogbo wa la ti gbọ nipa iṣẹlẹ ajalu to waye nile ẹkọ girama ti Ilugun to wa ladugbo Ẹlẹga. A ti fidi rẹ mulẹ pe otitọ ni iṣẹlẹ naa waye.
“Lorukọ ijọba ipinlẹ Ogun, a n ba awọn ẹbi to padanu ọmọ wọn kẹdun. Ohun to ṣẹlẹ yii ba wa lọkan jẹ gidi, ti a si gbadura pe bi Ọlọrun ṣe n tẹ ọmọ naa si afẹfẹ rere, ki Ọlọrun bu ororo itura si ọkan wọn
Afọlabi Babalọla.
A wo ori itakun awọn akẹkọọ wa, o si jẹ kayeefi wi pe orukọ awọn ọmọ naa ko si nibẹ, eyi fi han wi pe ọna alumọkọrọyi ni wọn fi gba awọn ọmọ naa wọle
Bakan naa la tun ṣakiyesi pe ọga ile ẹkọ awọn ọmọ yii n gba owo ti ko tọ lọwọ wọn, ninu iwadii ti a ṣe.
Ijọba ti wa jawe gbele ẹ fun awọn ọga ile ẹkọ mejeeji yii, titi digba ti a maa fi pari awọn iwadii wa lẹkunrẹrẹ.
“Ṣugvọn ṣa, iwadii ti a ṣe sọ ohun to yatọ nipa nnkan ti wọn n gbe kaakiri. Ọmọdekunrin to padanu ẹmi rẹ yii kii ṣe ojulowo akẹkọọ ile ẹkọ naa.
“Orukọ mẹta ọtọọtọ ni wọn fi pe ọmọ yii, bi awọn kan ṣe darukọ rẹ bii Babalọla Ayọmide, lawọn miran pe e ni Salakọ Jimọh, ti awọn miran si tun pe orukọ rẹ ni Afọlabi Babalọla. Sibẹ , ko si eyikeyi ninu orukọ naa to wa lori itakun akọsilẹ orukọ awọn akẹkọọ ti OGSERA fun ile ẹkọ naa, eyi ti a ni lọwọ.
"Eleyi ṣafihan pe ọna ẹburu ni wọn gba lati gba ọmọ naa wọle sile ẹkọ ọhun. Ni afikun, a tun ṣakiyesi pe ọga ile ẹkọ awọn kekere n gba owo aitọ lọwọ awọn akẹkọọ.
“Fun idi eyi, ijọba ti pinnu lati jawe gbele ẹ fun ọga ile ẹkọ agba ati kekere titi digba ti a o fi ṣewadi lati mọ kulẹkulẹ ohun to ṣẹlẹ.”
Siwaju sii lo jẹ ko di mimọ pe ijọba ti gbe eto kan dide ti yoo maa tu aṣiri awọn ile ẹkọ ti wọn ti n ṣiṣẹ ibi labẹ ileeṣẹ to n ri sọrọ eto ẹkọ tii ṣe TESCOM.
O rọ awọn akẹkọọ lati ṣe suuru, ki wọn si dẹkun biba dukia ijọba, paapaa dukia ile ẹkọ jẹ, ati pe enile tọwọ ba tẹ, yoo foju winna ofin.
No comments:
Post a Comment