Olu tiluu Orile-Ilawọ nipinlẹ Ogun, Ọba Alexander Olusegun MacGregor ti ba gbogbo ọmọ orileede Naijiria yọ lori ayajọ ọjọ ominira ti wọn n ṣe kaakiri ilẹ naa.
Ọba MacGregor to ṣayẹyẹ ọdun keji lori itẹ laipẹ yii, ninu ọrọ rẹ fun ayajọ ominira sọ pe awọn ọmọ Naijiria ni lati fi ọkan wọn jin fun orileede wọn.
Ninu atẹjade ikini ti Kabiyesi pe akori rẹ ni "Ọrọ ireti ati ojuṣe lori ayajọ ọjọ ominira Naijiria", Ọba MacGregor so
ọrọ rẹ, Kabiyesi naa jẹ ko di mimọ pe onikaluku lo ni ojuṣe ninu idagbasoke ilẹ Naijiria.
"Ni ayajọ ọjọ ominira orileede wa, emi Oba (Ọjọgbọn) Olusegun Alexander MacGregor, Olu tiluu Orile-Ilawo, fi ọrọ ibaniyọ mi ranṣẹ si gbogbo ọmọ Naijiri, nile ati loke okun.
"Kii ṣe pe ayajọ oni tọka si irin ajo ọjọ pipẹ nibi ti a ti n bọ nikan, bi ko ṣe pe o tun ṣafihan anfaani lati wo ẹyin wo nibi ti a ti n bọ, ki a si ṣajọyọ ifarada, ifarajin ọtun si awọn irọnu rere to so gbogbo wa papọ gẹgẹ bi eeyan.
"Bi a ti n ṣe iranti irubọ ti awọn akọni wa atijọ ti ṣe sẹyin, awa iran asiko yii ni lati duro ṣinṣin lori otitọ ati ohun idanimọ wa, ka si maa ṣe ododo ninu gbogbo nnkan ti a ba n ṣe.
"Ẹ jẹ ka wa ni iṣọkan ninu gbogbo adawọle wa, ka si maa bọwọ fun ara wa, leyi to ṣe pataki si idagbasoke ati ilọsiwaju apapọ. Igbiyanju agbajọwọ wa, ko si bo ti le kere to, o n ko ipa to pọ ninu idagbasoke awujọ wa.
"Si awọn ijọba wa, mo n fi tọkantọkan pe wọn si akiyesi lati maa ro awọn ọdọ alakikanju wa lagbara. Awọn ni ọjọ iwaju orileede wa, ti wọn si kun fun oniruuru ọgbọn ati imọ, paapaa imọ agbelẹrọ igbalode, ati agbara.
"Ẹ maa dokoowo sinu eto ẹkọ wọn, ẹ maa pese oriṣiriṣi anfaani iṣẹ fun wọn, ẹ gbaruku ti ọrọ iṣẹ ọwọ wọn, ki ẹ si pese agbegbe to dara, eyi ti yoo jẹ ki ala rere wọn wa si imuṣẹ, lati le jẹ ki Naijiria ṣe rere.
"Mo gbaguda pe ki ayajọ Ominira yii jẹ ka le ṣiṣẹ papọ, ka si di alafo, ka si le jọ kọ orileede ti alaafia, otitọ ati ilọsiwaju yoo jọba."
No comments:
Post a Comment