Iwe ẹri dukia ati ilẹ dirọrun ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, October 21, 2025

Iwe ẹri dukia ati ilẹ dirọrun ni Kwara


Lati le jẹ ki awọn araalu ri iwe ẹri dukia wọn gba lọwọ ijọba, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti fi ikanni igbalode lelẹ, eyi ti yoo jẹ k'awọn araalu tete ri iwe ẹri 'emi ni mo ni dukia', (CofO) wọn gba lasiko.

Ikanni yii ni wọn ṣagbekalẹ rẹ lati mu idagbasoke ba ilana agbekalẹ bi awọn iwe ẹri naa ṣe n jade.

Bakan naa, igbesẹ yii ni yoo tun jẹ ki iwe ẹri naa tete jade laaarin ọsẹ meji si oṣu kan, lẹyin ti awọn to ba forukọsilẹ ti gbe igbesẹ to yẹ ki wọn gbe.

“Oni yii jẹ igbesẹ aṣeyọri ninu ifarajin wa si imọ ẹrọ ati ṣiṣe ohun amuyẹ nidi iṣẹ ijọba,” Gomina AbdulRazaq sọ bẹẹ.

Gomina ṣalaye pe fun ọpọlọpọ ọdun, ilana atọwọdọwọ ni ọpọ ipinlẹ n lo lati fi ṣagbekalẹ iwe ẹri naa, nipa iforukọsilẹ, leyi to sọ pe o maa n fa ọpọ ifasẹyin ba awọn araalu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI