Ṣikun bayii lọwọ palaba ọkunrin kan to n pe ara rẹ ni Wolii segi, lori ẹsun ifipabanilopọ.
Ajayi Oluwatoyin ni wọn pe orukọ ọkunrin naa, ẹni ti wọn lo fipa ba ọmọdebinrin, ọmọ ogun ọdun to jẹ akẹkọọ fasiti ipinlẹ Ekiti laṣepọ.
Gẹgẹ bi ọga ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Joseph Eribo ṣe sọ lasiko to n foju afurasi naa han fawọn akọroyin lopin ọsẹ to kọja yii, o ni ọmọdebinrin naa lo fi iṣẹlẹ ọhun to ọlọpaa leti.
Iṣẹ irapada ni wọn sọ pe Ajayi fi tan ọmọ naa ti a fi orukọ bo laṣiri, to si ṣe bẹẹ fipa ba a laṣepọ. Ipele akọkọ ti a mọ si 100level ni wọn lọmọbinrin naa wa ni fasiti ipinlẹ Ekiti.
Ọga ọlọpaa naa tun foju awọn afurasi ọdaran miran han fawọn akọroyin, to si ni ọwọ palaba wọn segi kaakiri ipinlẹ naa, ninu iṣẹ aabo ti wọn yan laayo.
Lara awọn tọwọ tẹ naa ni wọn n digunjale, ti awọn miran si n lo ibọn lai gba iwe aṣẹ.
"Niluu Iworoko Ekiti, ẹnikan to n pe ara rẹ ni Wolii, Ajayi Oluwatoyin, lọwọ tẹ lori ẹsun wi pe o fipa ba ọmọdebinrin, ọmọ ogun ọdun to jẹ akẹkọọ fasiti ipinlẹ Ekiti laṣepọ,” ọga ọlọpaa sọ bẹẹ.
O ni ọwọ tun tẹ afurasi meji, Bọlaji Kazeem ati Isa Sikirulahi, pẹlu ibọn ilewọ agbelẹrọ ati ọta ibọn, to fi mọ aake.
Ọga ọlọpaa jẹ ko di mimọ pe ori ọkada lawọn mejeeji wa ti awọn ọlọpaa fi da wọn duro lati beere ọrọ lọwọ wọn, ko to di pe aṣiri wọn tu, iyẹn lagbegbe Isato to wa niluu Ado-Ekiti.
Siwaju sii lo ṣalaye pe ninu iwadii ni ọlọpaa tun ti gba ọkada kan ti wọn jigbe, eyi ti wọn tọju sahamọ wọn ni Omisanjana.
Lara awọn miran tọwọ tun tẹ ni Abọlaji Raṣheed tawọn eeyan n pe ni B.J, ẹni to wa lati ilu Owena nipinlẹ Ọṣun.
Asiko ti Abọlaji n gbiyanju lati ji ọkada gbe loju ọna Igbara Odo to wa ni Ọgọtun-Ekiti laṣiri rẹ tu, ti ọwọ palaba rẹ si segi, bo tilẹ jẹ pe awọn yooku rẹ na papa bora.
Awọn miran tun ni Mohammed Jamiu ati Ahmẹd, ti ọwọ tẹ lori ẹsun wi pe wọn ji ọkọ akẹru, Toyota Cabster gbe nibi ti olowo rẹ gbe e si ni garaaji Tipa [Tipper Garage] to wa lagbegbe Ijigbo niluu Ado-Ekiti.
Bakan naa lo tun fidi rẹ mulẹ pe ọwọ tun tẹ Ajetunmọbi Ayọmide lagbegbe Aramoko, ẹni ti wọn lo fipa ja ibale ọmọdebinrin, ọmọ ọdun mẹjọ, ati pe ọpọ igba lo ti ba ọmọ naa laṣepọ, ko to di pe aṣiri rẹ tu.
No comments:
Post a Comment