Wọn ni 'bi ko ba nidi, obin kii jẹ kumolu', gbajumọ olorin takasufee ilẹ South Africa nni, Black Coffee lo mọ ohun ti oju rẹ ti ri, ko too ṣe ipinnu to ṣẹṣẹ fi sita laipẹ yii.
Ọkunrin naa lo jẹ ko di mimọ pe oun ko tun jẹ fẹ iyawo miran mọ nigbesi aye oun.
Ọpọ awọn to gbọ ọrọ gbajugbaja onkọrin tawọn eeyan n gba tiẹ lasiko yii lorileede South Africa lo ṣi n ya lẹnu titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii.
Black Coffee, baba ọlọmọ mẹrin naa ti wa jẹ ko di mimọ pe oun ti ni oye iru ẹni toun jẹ, toun ko si le jẹ ki ọrọ biba ẹgbẹ pe ti oun nitikuti.
Ọkunrin dudu naa lo ṣalaye ohun ti oju rẹ ti ri lasiko to n dahun ibeere lori ikanni ayelujara, to si ni ọpọ igba lawọn obi oun ti n da oun laamu lati fẹ iyawo, paapaa latigba toun ti di olowo ati gbajumọ lawujọ.
“Nko tun jẹ fẹ iyawo mọ. O ti fi han gbangba, ati pe nitori pe mo ti wa nibi to dara, mo ti ni oye iru ẹni ti mo jẹ. Mo tun ni oye iru wahala ti mo n koju lati ọdọ awọn eeyan, lai jẹ pe wọn yoo ti yin lẹyin,” o ṣalaye.
“Pẹlu iṣẹ oojọ mi yii, paapaa julọ nigba ti ko tii di ohun mimọ, iyẹn ni pe nigba ti nko tii mọ boya mo maa kawe gboye lati di agbẹjọro. Ko tii dohun mimọ, ṣugbọn ni kete to di ohun mimọ, gbogbo eeyan lo n ya lẹnu. Mo ra ile ati ọkọ akọkọ mi, o si n ya awọn obi lẹnu, ti wọn fi n sọ pe ‘igba wo ni maa fẹ iyawo?'”
Ọdun 2019 ni Black Coffee ati iyawo rẹ tẹlẹ to tun jẹ oṣere tiata, Enhle Mbali Mlotshwa pin gaari, lẹyin ti wọn fẹsun aṣemaṣe kan an.
O ti wa jẹ ko di mimọ pe, o tẹ oun lọrun lati maa da gbe, lati le jẹ ki oun pẹ nidi iṣẹ toun yan laayo naa.

No comments:
Post a Comment