Ko saaye mọ fawọn ọdaran ati ajinigbe ni Kwara - Gomina AbdulRazaq ṣeleri - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, October 1, 2025

Ko saaye mọ fawọn ọdaran ati ajinigbe ni Kwara - Gomina AbdulRazaq ṣeleri


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara ti sọ ọ di mimọ pe ko si ibikibi ti yoo gba awọn ọdaran ati awọn ajinigbe mọ nipinlẹ naa, nitori pe opin ti de ba iṣẹ buruku wọn.

AbdulRazaq sọ pe aabo emi ati dukia araalu kaakiri ipinlẹ naa jẹ ijọba oun logun gidi, fun idi eyi, o ni iṣakoso oun ko ni faaye gba eyikeyi iwa ọdaran, paapaa awọn ajinigbe ni Kwara.

Gomina naa lo sọ eyi nibi ipade to ṣe pẹlu awọn ọga agba lẹka eto aabo, eyi to waye lalẹ ọjọ Iṣẹgun to kọja yii.

Lẹyin ikọlu to waye bi Oke Ode, Gomina AbdulRazaq ṣe ipade pẹlu Aarẹ Bola Ahmed Tinubu, ni bi to ti tọrọ fun awọn ẹṣọ aabo labẹ iṣakoso ijọba apapọ.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin gomina, Rafiu Ajakaye fi sita, Gomina AbdulRazaq jẹ ko di mimọ pe olu ileeṣẹ ologun ti gbe ọga agba (GOC) ti ileeṣẹ wọn, ẹkun keji tiluu Ilorin, lati le jẹ ki eto aabo tubọ lokun sii.

"Lalẹ ọjọ Aje, apapọ ileeṣẹ ologun, ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ, ati ọlọpaa ṣe ikọlu si agbegbe Baba Sango to wa loju ọna ẹnubode Kwara si Kogi, nibi ti wọn ti pa awọn agbesunmọmi mẹẹdogun.

"Ikọlu kan naa lo tun ṣẹlẹ lalẹ ọjọ Iṣẹgun. Ati pe ni alẹ ana, mo dari ipade igbimọ eto aabo to waye ni ile Ahmadu Bello tiluu Ilorin, lati ṣamulo awọn ohun ini ijọba apapọ ati tipinlẹ fun anfaani agbegbe Ariwa ati Guus Kwara."

Gomina loun fọkan araalu balẹ wi pe iṣakoso oun yoo maa ṣe iranwọ to ba yẹ lati le jẹ ki aabo wa fun gbogbo araalu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI