Ika abamọ ni baale ile, ẹni ọdun mọkandinlaadọta ti wọn pe orukọ rẹ ni Azeez Lamidi mu sẹnu nigba ti ile-ẹjọ paṣẹ pe ki wọn lọ fi sọgba ẹwọn titi digba ti ẹjọ rẹ yoo fi pari.
Lamidi ti wọn lo yan iṣẹ agbẹ laayo la gbọ pe o fipa ja ibale ọmọdebinrin ọmọ ọdun mẹtala kan ti a fi orukọ bo laṣiri.
Yatọ si pe Lamidi ja ibale ọmọ ọhun, wọn lo tun fun un loyun, to si tun n wa gbogbo ọna lati yọ oyun naa, ki aṣiri ma ba a tu sita.
A gbọ pe oniruuru oogun ni Lamidi ti fun ọmọ ọhun lati fi yọ oyun naa, ko to di pe aṣiri rẹ tu, iyẹn nigba tọrọ fẹẹ yiwọ.
Gbogbo ẹbẹ ti wọn ni Lamidi n bẹ Onidajọ Taiwo Lebi, lo ja si pabo, ti adajọ naa si ni ki wọn lọ fi pamọ sọgba ẹwọn Olokuta titi di ọjọ kejidinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2025 ti igbẹjọ yoo waye.
Onidajọ Lebi sọ pe ko too to asiko naa, awọn yoo ti gba amọran lati ọdọ ajọ Director of Public Prosecutions, (DPP), leyi ti yoo sọ ibi ti wọn yoo dari ẹjọ ọhun si.
Iya ọmọ naa, Arabinrin Salami la gbọ pe o lọ fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa Ọgbagi leti lọjọ kẹsan, oṣu yii, to si ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fun wọn.
Obinrin naa sọ pe niṣe ni ọmọ oun n da ẹjẹ labẹ, lasiko ti Lamidi gbiyanju lati yọ oyun fun un.
Loju ẹsẹ lawọn ọlọpaa lọ fi kele ofin gbe Lamidi nile rẹ to n gbe lojule kẹrinlelọgọta, adugbo Eegun, Ogbagi-Akoko, ipinlẹ Ondo.
Nigba to n tako Lamidi niwaju ile-ẹjọ, Agbefọba Martins Olowofeso, sọ fun ule-ẹjọ pe ẹsun ti wọn fi kan afurasi naa lo tako ipin kinni ati ikeji ni abala kẹta ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo, to sọ nipa ifipabanilopọ, ti ọdun 2021.
Ṣugbọn nigba to n tako ẹsun ti wọn fi kan an, Lamidi ṣalaye pe irọ nla to jinna si otitọ ni wọn pa mọ oun, ati pe ayalegbe oun ni baba ọmọ naa tẹlẹ, to si loun ti le wọn danu nigba ti iya ọmọ ọhun ati iyawo oun ja.
Lamidi sọ pe lọjọ ti wọn n sọ yii, inu oko loun wa, to si ni boun ṣe maa n lọ laaarin agogo meje aarọ si marun-un irọlẹ niyẹn, ati pe oun ko foju kan ọmọ ọhun lasiko naa.
“Ayalegbe ni baba ọmọ naa jẹ si mi lọdun 2022. Wọn kuro nile mi lẹyin ti wọn ni gbolohun asọ pẹlu iyawo mi. Nko foju kan wọn lọjọ ti wọn n sọ yii, inu oko mi ni mo wa, ti mo ti n ṣiṣẹ,” o ṣalaye bẹẹ fun ile-ẹjọ.

No comments:
Post a Comment