Ikunlẹ abiyamọ o! Gbajumọ olorin Naijiria ku kẹyin to jẹ majele lode ariya - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, October 20, 2025

Ikunlẹ abiyamọ o! Gbajumọ olorin Naijiria ku kẹyin to jẹ majele lode ariya


Ariwo ibanujẹ nla lo tun sọ lagboole amuludun nigba ti wọn kede iku gbajugbaja olorin ibilẹ nni, John Zuya, ẹni tọpọ mọ si John Mai Molo.

Zuya ni iroyin sọ pe ijọba ibilẹ Tafawa Balewa to wa nipinlẹ Bauchi ni wọn ti fi majele sinu ounjẹ rẹ, to si gbabẹ sọda sọrun alakeji.

Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2025 ti a wa yii la gbọ pe oloogbe naa pada sile, lati ilu Ekoo, to ti lọ ṣere fawọn ololufẹ rẹ ni oriṣiriṣi ode ariya.

Gbara ti wọn lo pada de sile, lo bẹrẹ sii sọ pe oun ko mọ bi ara ti n ṣe oun, iyẹn to jẹ ounjẹ ti wọn fura si pe majele wa ninu rẹ tan.

Loju ẹsẹ ni wọn ti sare gbe e lọ sile iwosan awọn olukọni ti Abubakar Tafawa Balewa University Teaching Hospital (ATBUTH) to wa niluu Bauchi, nibi ti wọn ti fidi rẹ mulẹ pe ẹlẹmi ti gba a.

Akẹgbẹ oloogbe naa, to si tun jẹ ọrẹ rẹ timọtimọ, Emma Wakili, lo fidi iroyin iku oloogbe naa mulẹ lori ikanni ayelujara ti Facebook, to si fidi rẹ mulẹ pe nnkan bi agogo meje aarọ lo dakẹ lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2025.

His body has been deposited in the hospital’s mortuary for autopsy as investigations continue into the cause of death.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI