L'Ọjọbọ, ọsẹ yii ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ṣabẹwo si agbegbe Oke Ode to wa nijọba ibilẹ Ifelodun lati ba awọn eeyan kẹdun lori ikọlu awọn ajinigbe to ṣẹlẹ laipẹ yii.
Nibẹ ni gomina ti fọkan awọn ara agbegbe ọhun balẹ wi pe awọn ileeṣẹ eleto aabo ti bẹrẹ iṣẹ lakọtun, lati maa daabo bo wọn.
Gomina sọ pe ẹdun ọkan lo jẹ foun wi pe awọn eeyan padanu ẹmi wọn sọwọ awọn ajinigbe ọhun.
Nigba to n gbadura pe ki Ọlọrun tẹ awọn to ku naa safẹfẹ rere, o loun nigbagbọ pe gbogbo ikolọ wọn yoo pada, ati pe alaafia yoo tun jọba bakan naa.
Siwaju sii ni gomina fi ọrọ ibanikẹdun ranṣẹ si awọn agbegbe lati Ifelodun lọ titi de Irepodun, Isin, Ekiti, Edu, ati Patigi.
“A ti wa lati ba gbogbo ẹyin ara agbegbe yii kẹdun lori awọn ikọlu to waye. Bakan naa lati tun gbe oriyin fawọn oṣiṣẹ eleto aabo ati awọn fijilante ti wọn tete dude lati koju, ti wọn si da alaafia pada,” gomina sọ bẹẹ.
“Ipenija nla lo jẹ. Ohun gbogbo lati fi si ojuṣe lati rii pe iru ikọlu bẹ ko tun waye mọ."
Lara awọn to kọwọrin pẹlu gomina ni ọga ọlọpaa, Adekimi Ojo; alakoso ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ; Sifu Difẹnsi, Ọmọwe Umar Mohammed; oluranlọwọ fun gomina lori eto aabo, Muyideen Aliyu; ati alaga ijọba ibilẹ Ifelodun, Ọnarebu Femi Yusuf; ati awọn miran.
No comments:
Post a Comment