Lati le jẹ ki aridaju wa pe iṣẹ idagbasoke n tẹsiwaju, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara ti ṣafihan bi atunkọ papa iṣere ilu Patigi yoo ṣe ri sita.
Ninu atẹjade ti amugbalẹgbẹ pataki fun gomina lori eto iroyin igbalode, Kọmureedi Olayinka Fafoluyi fi sita, o ni iṣẹ atunkọ naa ti bẹrẹ ni pẹrẹu.
Fafoluyi, tọpọ awọn eeyan tun mọ si Solace jẹ ko di mimọ pe ololufẹ ere idaraya ni Gomina AbdulRazaq, to si n ṣagbatẹru ni gbogbo igba.
O ṣalaye pe inu oṣu Kẹsan, ọdun 2025 ti a wa yii ni igbimọ iṣakoso ipinlẹ Kwara buwọ lu atunkọ papa iṣere naa si ti igbalode, lati le mu ilọsiwaju ba eto ere idaraya.
Lara awọn atunṣe ati ayipada ti yoo waye ninu papa iṣere ọhun ni ina mọnamọna ti kii ṣẹju, fifẹ ori papa, omi ti yoo maa wẹ koriko ori papa, koriko amutọrunwa, ati omi ẹrọ igbalode ti yoo maa ba oorun ṣiṣẹ.
Yatọ si eyi, ori papa iṣere naa yoo tun fẹ lọna ti yoo ba awọn akẹgbẹ rẹ lagbaye mu, gẹgẹ bo ti yẹ.
Oniruuru agbatẹru ni Gomina AbdulRazaq ti ṣe fun ẹka ere idaraya, lara rẹ ni atunṣe papa iṣere ipinlẹ Kwara, ati awọn miran.

No comments:
Post a Comment