Ile-ẹjọ kan niluu Abuja ti da ajọ Petroleum and Natural Gas Senior Staff Association of Nigeria (PENGASSAN) lọwọ kọ lati gun le iyanṣẹlodi ti wọn n gbero lati bẹrẹ.
Bi ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii ni awọn alakoso PENGASSAN sọ pe awọn yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi lati tako igbesẹ tu ileeṣẹ ifọpo Dangote, iyẹn Dangote Petroleum Refinery and Petrochemicals FZE.
Onidajọ Emmanuel Sublim, to gbọ ẹjọ naa lọjọ Aje, ọsẹ yii paṣẹ pe PENGASSAN ko gbọdọ gun le iyanṣẹlodi kankan, nitori pe niṣe ni wọn n gbero lati da iṣẹ duro nileeṣẹ Dangote, ati lati fopin si bi wọn ṣe n ko epo rọbii ati afẹfẹ gaasi wọ ileeṣẹ naa.
Ile-ẹjọ sọ pe igbesẹ ti ajọ PENGASSAN fẹẹ gbe naa ni lati ba eto ọrọ aje Naijiria jẹ, fun idi eyi, wọn ko gbọdọ tẹsiwaju.
Agbẹjọro ileeṣẹ ifọpo naa, George Ibrahim lo pe ẹjọ naa, lati da ajọ PENGASSAN lọwọ kọ lati gun le iyanṣẹlodi ti wọn n gbero.
Bakan naa ni ile-ẹjọ naa tun da awọn ileeṣẹ ati ajọ bii Nigerian National Petroleum Company Limited (NNPCL); Nigerian Midstream and Downstream Petroleum Regulatory Authority (NMDPRA), ati Nigerian Upstream Petroleum Regulatory Commission (NUPRC) lati mu aṣẹ ti ajọ PENGASSAN fi lelẹ lo nipa didawọ epo rọbii ati afẹfẹ gaasi duro.
Onidajọ Sublim sọ pe ohun ti ileeṣẹ Dangote n beere fun yẹ, nitori pe ohun to pe ba nnkan ti ko nii ni atunṣe jẹ ni.
Nigba ti ile-ẹjọ naa sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹtala, oṣu Kẹwa, ọdun yii, bẹẹ lo ni ki ohun gbogbo wa bo ṣe wa tẹlẹ titi digba naa.
No comments:
Post a Comment