AbdulRazaq, Abiọdun kẹdun iku Ṣẹgun Awolọwo to doloogbe - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, November 21, 2025

AbdulRazaq, Abiọdun kẹdun iku Ṣẹgun Awolọwo to doloogbe


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara ati Gomina Dapọ Abiọdun tipinlẹ Ogun ti ba idile Awolowo kẹdun iku Ṣẹgun Awolọwo, ọmọ-ọmọ agba oṣelu nni, Oloogbe Obafemi Awolowo.

Segun Awolowo to fi figba kan ri jẹ alakoso agba fun ileeṣẹ Nigerian Export Promotion Council ni igba meji ọtọọtọ, lo dagbere faye lẹyin aisan rampẹ.

Nigba to n kẹdun iku oloogbe naa, Gomina AbdulRazaq ṣapejuwe oloogbe gẹgẹ bi ọmọ Naijiria rere to wa ilọsiwaju fun ilẹ naa.

Gomina AbdulRazaq ni ẹdun ọkan lo jẹ pe wọn padanu ọkan lara awọn ogo ilẹ Naijiria, ẹni to ti ko ipa pataki ninu idagbasoke eto ọrọ aje ilẹ naa.

Ọjọbọ, ọsẹ yii ni oloogbe naa jade laye lẹni ọdun mejilelọgọta.

“Ọrẹ timọtimọ ni Segun jẹ si mi nigba aye rẹ, o si jẹ oṣiṣẹ to farajin fun ilọsiwaju, koda to tun ko eeyan mọra. Iku rẹ ba ni lọkan jẹ, ti a si maa ṣafẹri gidigidi, nipa awọn ohun to duro fun,” AbdulRazaq sọ bẹẹ.

Bakan naa ni Gomina Abiodun, nigba toun naa n kẹdun sọ pe ọkan pataki lara awọn ọmọ ipinlẹ Ogun lo fi aye silẹ lasiko ti awọn nilo rẹ julọ.

O sọ pe bi baba rẹ, Obafemi Awolowo ṣe farajin fun ilọsiwaju Naijiria, naa ni Segun funra rẹ farajin fun itẹsiwaju.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI