Nibi ipade naa ni Gomina AbdulRazaq ti rọ gbogbo awọn olori eleto aabo naa lati tubọ gbajumọ ọrọ eto aabo, lati daabo bo ẹmi ati dukia araalu.
Ipade naa lo waye lori ikọlu to waye lagbegbe Eruku lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii, nibi ti awọn bandiiti ti ṣe ikọlu sile ijọsin CAC, iyẹn nijọba ibilẹ Ekiti.
Nigba to n bawọn eeyan sọrọ, ọga ọlọpaa, Ojo Adekimi sọ pe awọn ti bẹrẹ igbesẹ to yẹ lati dena irufẹ ikọlu to waye laipẹ yii.
O ni gbogbo awọn to lọwọ ninu ikọlu naa lọwọ yoo tẹ laipẹ ọjọ, ti wọn yoo si gba awọn to wa lahamọ wọn kalẹ kuro ninu ahamọ.
No comments:
Post a Comment