Lati ba awọn ara agbegbe Eruku ti awọn agbesunmọmi ti a mọ si bandiiti ṣe ikọlu si laipẹ yii kẹdun, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara ti ba gbogbo araalu naa kẹdun.
Gomina AbdulRazaq lo kede wi pe oun ti ṣabẹwo ibanikẹdun si agbegbe Eruku naa nijọba ibilẹ Ekiti, toun si ṣepade pẹlu ẹgbẹ ọmọ lẹyin Jesu, CAn ati awọn araalu naa.
Nibẹ ni gomina ti fọkan awọn araalu naa balẹ pe iya to jẹ wọn laipẹ yii ko nii lọ lasan, ati pe ijọba yoo gbẹsan lara awọn igara ọlọṣa naa.
Laipẹ yii ni awọn bandiiti ṣe ikọlu nla si ile ijọsin Christ Apostolic Church, ti wọn si pa awọn eeyan nipakupa, ti wọn tun ji awọn miran gbe salọ.
Lara awọn to kọwọrin pẹlu gomina ni ọga ọlọpaa ipinlẹ naa, Ojo Adekimi, ọga ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ, ati awọn aṣoju ijọba lati ba awọn eeyan kẹdun.
Gomina sọ nibẹ pe ẹdun ọkan nla ni ikọlu ọhun jẹ fun ipinlẹ Kwara, to si ni ijọba ti bẹrẹ igbesẹ lati koju awọn bandiiti naa.
Bakan naa ni gomina tun fi aidunnu rẹ han lori ikọlu awọn agbesunmọmi si awọn agbẹ niluu Bokungi, ijọba ibilẹ Edu.
Siwaju sii ni gomina tun ṣabẹwo si aafin ọba Owa tiluu Eruku, Ọba Busari Olarewaju ati ile ijọsin naa.
No comments:
Post a Comment