Adanu nla niku Ọgagun Abdullahi Adangba jẹ fun Kwara - Gomina AbdulRazaq kẹdun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, November 5, 2025

Adanu nla niku Ọgagun Abdullahi Adangba jẹ fun Kwara - Gomina AbdulRazaq kẹdun


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara ti kẹdun iku Ọgagun Abdullahi Adangba to jade late lẹni ọdun mẹrindinlaadọrun.

Ọmọ bibi ilu Ilorin, ipinlẹ Kwara la gbọ pe o jade laye lẹyin aisan rampẹ to nii ṣe pẹlu ti ọjọ ogbo.

Yatọ si pe oloogbe naa ti figba kan ri jẹ olori ninu iṣẹ ologun, o tun ti ṣe gomina ipinlẹ Benue ati Plateau,bẹẹ lo tun ti ṣe alakoso ileeṣẹ to n ri sọrọ aabo apapọ.

Bakan naa lo tun ti jẹ oludamọran pataki fun olori ologun nigba kan ri, Ọgagun  Abdulsalami Abubakar; to si tun ti ṣiṣẹ papọ gẹgẹ bi olori awọn oṣiṣẹ Aarẹ Olusegun Obasanjo ati Umar Musa YarAdua; pẹlu awọn ipo nla miran to ti di mu.

Gomina AbdulRazaq jẹ ko di mimọ pe adanu nla ni iku agba alẹnulọrọ naa jẹ fun ilu Ilorin, to si n gbadura pe ki adẹdaa tẹ ẹbsi afẹfẹ rere.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI