Ko si ireti kankan mọ f'ẹgbẹ oṣelu PDP lati pada sipo agbara - Fayose pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 3, 2025

Ko si ireti kankan mọ f'ẹgbẹ oṣelu PDP lati pada sipo agbara - Fayose pariwo sita

Gomina tẹlẹri nipinlẹ Ekiti, Peter Ayodele Fayose ti sọ pe ipo aini ireti lẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party, PDP wa bayii lorileede Naijiria.

Fayose sọ pe ojiji ohun ti ẹgbẹ naa jẹ lọpọlọpọ ọdun sẹyin ni wọn n lo bayii, ti ko si tii sẹni to le ran wọn lọwọ.

Agba oloṣelu naa lo sọrọ yii lọjọ Aiku to kọja, lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Ado Ekiti.

O sọ pe pẹlu ipo ti ẹgbẹ PDP wa lasiko yii, ko si ireti kankan fun wọn lati de ipo agbara

“PDP ti wa ninu ipo ipo ani ireti, bẹẹ si ni wọn tun jẹ ojiji ara wọn. Ẹgbẹ PDP nilo adari kan ṣoṣo to le mu iṣọkan ati irẹpọ ba gbogbo ọmọ ẹgbẹ lasiko yii.

“Ko si ireti kankan mọ bayii wi pe PDP yoo pada wa nipo agbara. Koda awọn balogun ọkọ oju omi wa tun n fo ọkọ kọja. Wọn kuro lori ibusun kan bọ sibomiran. Ta wa ni yoo di ẹgbẹ naa mu lati pada bọ sipo,” Fayose sọ bẹẹ.

Bakan naa lo sọ pe ẹgbẹ naa ti lọ soko iparun, pẹlu bo ṣe ni iṣakoso Damagum gẹgẹ bi alaga igbimọ amuṣẹṣe jẹ agboku, to si jẹ ko di mimọ pe wọn wa lati gbe ẹgbẹ naa sinu koto patapata ni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI