Bi iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ṣe n ṣe agbelarugẹ fọrọ eto ẹkọ nipinlẹ Kwara, gomina naa ti wa jẹ ko di mimọ pe ko si ọmọ kankan ti wọn yoo fi silẹ lai kawe de ibi to lapẹrẹ.
Gomina AbdulRazaq ti jẹ ko di mimọ pe ko din ni aadọta ọmọde ti wọn ti wa labẹ anfaani eto ẹkọ ti iṣakoso oun n ṣagbatẹru eto ẹkọ wọn, lati le jẹ ki wọn ba ẹgbẹ pe.
Awọn ọmọ naa la gbọ pe wọn yoo kawe lati ipele aṣẹṣẹbẹrẹ titi de girama, pẹlu anfaani ounjẹ ọfẹ, aṣọ ọfẹ, to fi mọ awọn ohun elo ọfẹ ni wọn yoo lẹtọ si, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Pupọ awọn ọmọ wọnyi la gbọ pe awọn obi wọn ti pa ti sẹgbẹ opopona lati maa tọrọ owo tabi ounjẹ kaakiri, leyi ti ko bojumu to.
Kọmiṣanna feto ọrọ ilu, iyẹn Social Development, Hajia Mariam Nnafatima Imam, fidi iroyin yii mulẹ lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii niluu Ilorin, ipinlẹ Kwara.
Hajia Imam ṣalaye pe awọn ọna ni wọn ko si ọgba itọju awọn ọmọde, ti wọn pe ni Child Reception Centre (CRC), lati le maa gbọ bukata lori wọn, ki wọn ma ba a di idakuda lọjọ iwaju, ki wọn si le wulo fun ilu wọn lọjọ ọla.

No comments:
Post a Comment