Akẹkọọ Adekunle Ajasin meji wọ gau lori ẹsun ifipabanilopọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, November 25, 2025

Akẹkọọ Adekunle Ajasin meji wọ gau lori ẹsun ifipabanilopọ


Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti tẹ akẹkọọ meji nile ẹkọ fasiti Adekunle Ajasin University, AAUA, to wa niluu Akungba-Akoko, lori lilo egboogi oloro ati fifipa ba akẹkọọ-binrin ẹgbẹ wọn laṣepọ.

Gẹgẹ bi Olushola Ayanlade to jẹ agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa ṣe sọ, o ni niṣe ni afurasi naa tan ọmọbinrin ọhun lọ sile ọrẹ rẹ ọjọ to ti pe, Queen Sodo, ẹni ọdun mọkandinlogun, toun naa tun jẹ akẹkọọ ni fasiti ọhun.

O ni ọmọbinrin naa fọkan tan ọrẹ ti wọn ti n bọ lati ile-ẹkọ girama titi de fasiti naa, leyi to jẹ ko gba ọti ẹlẹrindodo lọwọ rẹ, lai mọ pe o fi fi oogun sinu rẹ.

Ayanlade jẹ ko di mimọ pe lẹyin ti ọmọbinrin naa mu ọti ọhun tan, ni ara rẹ bẹrẹ sii yatọ. Loju ẹsẹ ni Queen ti sare jade, to si lọ pe ọrẹkunrin rẹ to wa nitosi lati wa fipa ba a laṣepọ.

A gbọ pe ẹnikan to wa nitosi lo gbọ ariwo ti ko wọpọ lati inu yara wọn, to si sare wọle lati wo ohun to n ṣẹlẹ nibẹ. Si iyalẹnu, niṣe lo ba awọn mejeeji nihoho ọmọluabi.

Loju ẹsẹ ni wọn ti gbe ọmọbinrin naa lọ sile iwosan fun itọju, nibi to si ti n gba itọju lọwọ titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii.

Ayanlade sọ pe awọn afurasi mejeeji ni wọn ti jẹwọ ẹṣẹ wọn bayii, ti wọn si n bẹbẹ fun oju aanu.

Bakan naa lo sọ pe iwadii ṣi n tẹsiwaju pẹlu bi awọn mejeeji ṣe ti wa latimọle awọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI