Ijọba ipinlẹ Ogun ti sọ pe awọn ko nii kawọ gbera lori ọrọ gbajugbaja onkọrin nni, Ademọla Abiọdun tọpọ mọ si DJ Chicken, pẹlu bo ṣe n fi ọkọ ayọkẹlẹ rẹ ni ijamba kaakiri igboro.
Ileeṣẹ to n ri sọrọ eto idajọ nipinlẹ naa sọ pe awọn ti bẹrẹ igbesẹ lati rii pe awọn foju ọmọkunrin naa ba ile-ẹjọ lori ẹsun iwakuwa ati aile kora ẹni nijanu to n ṣe kaakiri.
Laipẹ yii ni Ademọla fi ọkọ rẹ kọlu awọn eeyan lẹẹmeji ọtọọtọ, eyi to jẹ kawọn araalu maa sọ pe ọrọ rẹ kii ṣoju lasan.
Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, wọn ni lọjọ kinni, oṣi Kọkanla, ọdun 2025 ni DJ Chicken fi ọkọ ayọkẹlẹ rẹ kọlu ọlọkada meji ọtọọtọ niluu Ṣagamu, ti ọlọkada naa ati obinrin kan si farapa yannayanna.
Wọn ni bo ṣe kọlu awọn eeyan naa, lo fẹ maa salọ, ko to di pe awọn ara agbegbe naa sare le e mu, ti wọn si bẹrẹ sii lu nilukulu.
Nigba naa, wọn lawọn ọlọpaa da si ọrọ naa, wọn si bẹrẹ iṣẹ iwadii, ninu eyi ti wọn tun ṣe itọju awọn to farapa naa.
Bakan naa, lọjọ kẹtalelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2025 kan naa, wọn sọ pe Ademọla tun lọ fi ọkọ ayọkẹlẹ rẹ kọju awọn eeyan lagbegbe Lekki, nipinlẹ Ekoo, bo tilẹ jẹ pe ori ko ẹnikan to n fẹsẹ rin lọ yọ.
Ijamba to ṣẹlẹ lọjọ Aiku naa, ni yoo jẹ ijamba ẹlẹẹkẹta ti ọmọkunrin naa yoo fi ọkọ rẹ ni laaarin oṣu meji gbako, ti wọn lọrọ rẹ n fẹ abojuto.
''Bo tilẹ jẹ pe ohun to ṣe pataki ni ki awọn ti wọn ba fi ọkọ gba, gba itọju, ki wọn si ṣe ẹtọ fun wọn, sibẹ awọn to n wa iwakuwa ni lati jiya ẹṣẹ wọn labẹ ofin iwa ọdaran,'' atẹjade ọhun sọ bẹẹ.
''Ọgbẹni Abiọdun wa lara awọn eeyan bẹẹ. O kere tan, ijamba meji ọtọọtọ la ri ninu fọnran to jade, leyi to fi aridaju han. Bi Abiọdun tun ṣe pade bẹrẹ sii wa ọkọ lai tii gba itọju to to, lẹyin ọsẹ mẹta jẹ eyi to yẹ ki ijọba dide si, lati le daabo bo awọn araalu - paapaa bi awọn eeyan ṣe ti bẹrẹ sii pariwo sita.''
Adajọ agba nipinlẹ naa, Oluwasina Ogungbade, SAN ti wa paṣẹ pe ki iwadii bẹrẹ lori ikọlu Ṣagamu, ki wọn si le tete foju rẹ ba ile-ẹjọ.

No comments:
Post a Comment