Ijọba ipinlẹ Kwara ti rọ awọn to n gbe iroyin ẹlẹjẹ kaakiri ori ayelujara lati lọ wabi jokoo si, nitori pe ohun ti ko ṣẹlẹ ni wọn n gbe kaakiri lati maa fi dẹru ba awọn araalu.
Wọn ni awuyewuye to n lọ kaakiri igboro wi pe awọn agbẹsunmọmi ti wọn tun n pe ni bandiiti ṣe ikọlu si agbegbe Isapa, ti wọn si ji awọn mọkanla, to fi mọ alaboyun gbe kii ṣe otitọ, bi ko ṣe iroyin agbelẹrọ lasan.
Iroyin ẹlẹjẹ naa ti wọn n gbe kaakiri ori ikanni Facebook, ni wọn sọ pe akọwe ipolongo ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), Sholyment Oluwasegun Olusola kọkọ gbe jade, ti iwe iroyin National Pilot naa si gbe e jade.
Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, wọn ni obinrin alaboyun kan wa lara awọn mọkanla ti wọn jigbe lagbegbe Isapa, koda ti wọn ni awọn meje lati inu mọlẹbi kan naa wa ninu wọn.

No comments:
Post a Comment