Lati ọwọ Owodunni Rasheed Adekunle
O foju han pe bi okiki ati ipa rere ti Oloye Fafoluyi Olayinka Michael, tọpọ awọn eeyan mọ si Solace, Amugbalẹgbẹ agba pataki fun gomina ipinlẹ Kwara lori eto iroyin igbalode ti n da agbo awọn alatako kan ru.
Pẹlu awọn akọsilẹ iṣẹ rere manigbagbe to ti ṣe, ati ifarajin rẹ si iṣẹ idagbasoke agbegbe, awọn alailoye kan ti wọn jẹ agba alailomininu ti wọn n pariwo lati ba orukọ rere naa jẹ, dipo ki wọn wa ọna lati ko ipa ti yoo mu idagbasoke ba awọn araalu.
Solace ti gbiyanju lati da yatọ gẹgẹ bi adari to ṣẹṣẹ n dide bọ, ti kii sii sọrọ idagbasoke lasan, bi ko ṣe pe ko gbe igbesẹ ti yoo ni apẹẹrẹ rere. Lati fifa anfaani idagbasoke wa si agbegbe, ati ṣiṣẹ agbatẹru iranlọwọ oniruuru iṣẹ idagbasoke fun awọn agbegbe, o ti fi han fawọn eeyan pe iṣẹ adari wa fun sinsin ilu ati awọn eeyan tọkantọkan, kii ṣe nipa iwa imọ-tara-ẹni-nikan.
Laarin ọdun yii nikan, ọkunrin naa ti ti fa awọn iṣẹ idagbasoke ina agboorun [solar-powered streetlights] kaakiri awọn agbegbe to wa ni wọọdu Rore, Aran-Orin, ati Ipetu. Yatọ si eyi, o tun ti ṣe omi ẹrọ igbalode, ati kikọ ileegbe awọn agunbanirọ Corpers' Lodge. Bẹẹ lo tun ṣagbatẹru idanilẹkọọ fawọn ọdọ ni IVTECH, leyi to ṣi anfaani iṣẹ ọwọ ati ironilagbara silẹ fawọn ọdọ.
Ko si eyikeyi ninu awọn akanṣe iṣẹ idagbasoke wọnyi ti ko ṣee foju ri. Lati le mọ riri awọn ipa to ti ko lawujọ, laipẹ yii ni wọn fi oye Akewejẹ tiluu Aran-Orin ati Aarẹ Bobájiròrò tiluu Oko-Irese da Solace lọla. Awọn oye wọnyi kii ṣe ti afẹfẹ yẹyẹ nikan, bi ko ṣe pe wọn jẹ ẹri si itẹwọgba awọn iṣẹ rere rẹ nipa ṣiṣe anfaani fawọn araalu.
Dipo ki wọn maa fi asiko ati awọn ohun amuṣọrọ ṣofo nipa ṣiṣe ikọlu ti ko lẹsẹ nilẹ, ki gbogbo awọn ti ọrọ naa n dun lọ kọ ẹkọ lori bi Solace ṣe n tayọ yatọ, ki wọn si rii gẹgẹ bi awokọṣe, ki wọn si dari gbogbo ipa wọn sori awọn ohun idagbasoke.
Oloye Fafoluyi Olayinka Michael Solace jẹ alafojusun lori ipinnu ti yoo mu itẹsiwaju ba idagbasoke fun awọn wọọdu Rore, Aran-Orin, ati Ipetu to wa nijọba ibilẹ Irepodun.
Awọn ọrọ rẹ ṣoju ṣaara: ko si si oniruuru ọrọ kugbakugbe to da iṣẹ rere rẹ duro, ati itara to ni fun iṣẹ idagbasoke lati mu ayipada rere wọle silu.
Owodunni Rasheed Adekunle to kọ apilẹkọ yii jẹ akọwe iroyin fun alaga ijọba ibilẹ Oyun nipinlẹ Kwara.






No comments:
Post a Comment