Aṣa, Irin-ajo afẹ goke agba ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 24, 2025

Aṣa, Irin-ajo afẹ goke agba ni Kwara


Pẹlu erongba lati mu itẹsiwaju ba eto irin ajo afẹ ati aṣa, ijọba ipinlẹ Kwara ti bẹrẹ atunṣe opopona Owu Falls to wa niluu Owa-Onire, ijọba ibilẹ Ifelodun.

Ninu atẹjade ti amugbalẹgbẹ pataki fun gomina lori eto iroyin ayelujara, Olayinka Fafoluyi fi sita, o ni iṣẹ akanṣe ti onidagbasoke ṣi n tẹ̀siwaju ni Kwara, labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq.

Fafoluyi sọ pe opopona Owu Falls naa ni wọn n ṣe lati jẹ ki eto ọrọ aje agbegbe naa tubọ ni idagbasoke.

O ni bi ibi igbafẹ naa ṣe gbajumọ to, ti awọn eeyan si n lọ sibẹ lati gbafẹ, sibẹ opopona ni iṣoro ti agbegbe naa n koju, to si ni ijọba ti dide lati koju iṣoro ọhun.

Bakan naa lo ni awọn agbegbe bii Owu-Isin, Babanla, Agbala, ati Afon to wa nitosi ni yoo jẹ anfaani naa.





No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI