Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Abiodun Gani Adams ti sọ pe ki gbogbo ọmọ ilẹ Yoruba wa ni ifura lasiko yii, nitori pe awọn agbesunmọmi ti wa kaakiri ẹkun Iwọ-Oorun Naijiria.
Iba Gani Adams lo sọrọ naa laipẹ yii niluu Eko nibi ifọrọwerọ to ṣe nileeṣẹ amohunmaworan Central TV.
Adams ni ọpọ agbegbe kaakiri ilẹ Yoruba ni awọn agbebọn ati agbesunmọmi ti wọ, ti awọn eeyan ko si fura nipa wọn.
O ni erongba wọn ni lati ṣe ikọlu si awọn araalu, paapaa nilẹ Yoruba, to si lawọn eleto aabo ni lati gbaradi, lati koju awọn oniṣẹ buruku yii.
“A ti wa ni asiko to jẹ pe eto aabo orileede yii ti n gba ironu ijinlẹ ati idaamu to gba ero gidi. Awọn iṣẹlẹ to n waye kaakiri awọn ipinlẹ kan lorileede yii ti ṣafihan pe Naijiria n koju idunkoko eto aabo,” Gani Adams sọ bẹẹ.
“Iroyin ti fidi rẹ mulẹ pe awọn agbebọn ti wa kaakiri ọpọ agbegbe nilẹ Yoruba, ti a ni lo lati wa ni ikiyesara.”
O fi kun ọrọ rẹ pe awọn ohun to ṣẹlẹ nipinlẹ Kogi ati Kwara ti jẹ ko di mimọ pe awọn ẹkun mejeeji ti wa ninu ewu nla, ti a nilo lati tete gbe igbesẹ to yẹ.
“Ohun ti wọn n ṣe ni Kogii ati Kwara ni lati ṣe idanwo lawọn agbegbe naa, ko to di pe wọn ṣe ikọlu nla ti wọn n gbaradi fun. Olobo to wa lọwọ wa fi han pe awọn ipinlẹ bii Oyo, Ekiti, Ondo, ati paapaa Eko ni wọn n lepa,” o tun sọ bẹẹ.
“Awọn ẹgbẹ kan naa yii ni wọn n ṣeku pa awọn eeyan kaakiri orileede yii. Nigba miran, wọn a pe wọn ni bandiiti, nigba miran, wọn a si tun pe wọn ni darandaran.
“Ṣugbọn ju eyi lọ, a mọ pe awọn agbebọn agbaye bii ISIS, ISWAP ati Boko Haram naa ni ṣiṣẹ buruku wọn nilẹ Naijiria. A tun ṣi ni awọn ọmọ miran ti wọn tun yapa kuro ninu awọn ẹgbẹ buruku wọnyi.”
O wa jẹ ko di mimọ pe awọn eeyan lati ilẹ okeere wa ninu awọn to n ṣakoso pupọ ninu awọn ẹgbẹ wọnyi, kii ṣe awọn ti Naijiria nikan.

No comments:
Post a Comment