Inu mi ko dun si bi wọn ṣe n pa awọn Kristiẹni ni Naijiria - Trump tun fibinu sọrọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, November 22, 2025

Inu mi ko dun si bi wọn ṣe n pa awọn Kristiẹni ni Naijiria - Trump tun fibinu sọrọ


Aarẹ ilẹ Amẹrika, Donald Trump tun ti fi aidunnu rẹ han si bo ṣe ni awọn kan n pa awọn ọmọ iya oun ninu ẹsin Kristiẹni nilẹ Naijiria, to si loun yoo dide lati gbeja wọn laipẹ.

Trump ninu ọrọ rẹ to sọ jade laipẹ yii, jẹ ko di mimọ pe ogunlọgọ awọn Kristiẹni ni wọn ti n pa danu lẹkun Iwọ Oorun ilẹ Afrika.

Ọjọ Ẹti, Fraide, ọsẹ yii ni Aarẹ ilẹ Amẹrika sọrọ naa lori eto to fi lọ farahan nileeṣẹ redio kan, eyi ti iwe iroyin Fox gbe jade.

Bi ẹ ko ba gbagbe, lọsẹ diẹ sẹyin ni Trump kede Naijiria gẹgẹ bi orileede to nilo iranlọwọ, to si n kọni lominu. Nigba naa, Trump sọ pe oun yoo gbe awọn ọmọ ogun ilẹ Amẹrika dide lati dawọ ikọlu ati ipaniyan naa duro nilẹ Naijiria.

Bakan naa ni Trump fẹsun kan ijọba Naijiria wi pe wọn kọ lati daabo bo awọn Kristiẹni lọwọ awọn musulumi apanijaye.

Nigba to n sọrọ lori igbesẹ ti yoo gbe, o ni o ṣee ṣe koun dawọ iranlọwọ to n wọ Naijiria duro.

Bakan lo ni bi ijọba Naijiria ba kọ lati gbe igbesẹ to yẹ lasiko, oun yoo gbe awọn ọmọ ilẹ Amẹrika lati dawọ ikọlu si awọn Kristiẹni naa duro.

“Orileede adojutini ni Naijiria. Gbogbo ohun to n ṣẹlẹ yii, idojuti nla gba a ni.

“Wọn n pa awọn eeyan logun-lọgọ. Ipani ẹlẹya kan lo jẹ, o si n bi mi ninu gidi. A sin san, ẹyin naa mọ, oniruuru ẹdinwo lati ṣe si Naijiria, ti a si maa dawọ rẹ duro laipẹ.”, o sọ bẹẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI