Ayédèrú dókítà wo wàhálà l'Ógùn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, November 22, 2025

Ayédèrú dókítà wo wàhálà l'Ógùn


Ọrọ Yoruba kan ti wọn maa n sọ wi pe 'ọjọ gbogbo ni ti ole, ọjọ kan ṣoṣo ni t'olohun', lo lọ nibamu pẹlu bọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ṣe tẹ ọdọmọkunrin, ẹni ọdun mejidinlọgbọn kan ti wọn ni ko niṣẹ meji ju ko maa fi iṣẹ dokita lu awọn obinrin ni jibiti lọ.

Victor Cletus ni wọn pe orukọ ọdọmọkunrin naa, ẹni ti wọn sọ pe ọpọ obinrin, paapaa awọn ọlọmọge lo ti lu ni jibiti owo ati abẹ, nipa ẹtanjẹ.

Ori ayelujara ni wọn sọ pe Victor ti maa n mu awọn onibara rẹ lati lu wọn ni jibiti

Ninu atẹjade ti Ọmọlọla Odutọla to jẹ agbẹnusọ ọlọpaa fi sita laipẹ yii, o ni bi Victor ba ti ri ẹni ti yoo lu jibiti lori ayelujara, yoo fi ọrọ tutu tan an ni ẹni naa yoo fi ko sii lọwọ.

Odutọla ni ọkan lara awọn ti Victor lu ni jibiti lo mu ẹjọ rẹ wa si teṣan, to si ṣalaye bi ọmọkunrin naa ṣe gba ọpọ owo lọwọ rẹ.

O ni Victor maa n sọ fawọn eeyan pe ile iwosan awọn olukọni ti Babcock, iyẹn Babcock University Teaching Hospital loun ti n ṣiṣẹ gẹgẹ bi akọṣẹmọṣẹ oniṣegun oyinbo.

''Ọmọbinrin kan lo wa fi ọrọ naa to wa leti, to si ṣalaye bi Victor ṣe ba a sọrọ lori ayelujara Snapchat, to si purọ pe onisegun oyinbo to n ṣiṣẹ ni Babcock loun jẹ. Nigba to gba gbogbo irọ naa gbọ tan, o si ṣalaye awọn iṣoro to ni ninu ọmu rẹ.

''Anfaani yii ni Victor lo lati fi bẹrẹ sii gba owo lọwọ ọmọbinrin naa, lati ṣiṣẹ abẹ fun un, to si ni ko wa pade oun lọjọ kẹjidinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2025 fun iṣẹ abẹ naa.

''Kaka ko ṣe iranwọ to tọ lẹka eto ilera, niṣe lo fẹ fi tipa ba a laṣepọ, to si tun ji owo lati inu apo aṣuwọn rẹ.''

Odutọla ni nigba to di ọjọ keji to yẹ ki wọn ṣiṣẹ abẹ naa, niṣe ni Victor bẹrẹ sii fọwọ tẹ ọmọbinrin naa lara, to si fẹẹ fi tipa ba a laṣepọ, idi ree ti ọmọbinrin naa fi kan si ile iwosan Babcock lati beere nipa Victor nibẹ.

''Si iyalẹnu, iṣẹ agbalẹ ni ọmọkunrin naa n ṣe, kii ṣe dokita rara,'' Odutọla ṣalaye.

Ni bayii, ọha ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Ogunlọwọ ti paṣẹ pe ki Victor wa lahamọ titi digba ti wọn yoo fi pari iwadii lori rẹ, lati mọ iye awọn to ti lu jibiti, ko to di pe wọn foju rẹ ba ile-ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI