Ẹ dakẹ rumọọsi! Ko sibi ti awọn bandiiti ti ṣe ikọlu loju ọna Iwo si Osogbo - Oluwoo pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, November 23, 2025

Ẹ dakẹ rumọọsi! Ko sibi ti awọn bandiiti ti ṣe ikọlu loju ọna Iwo si Osogbo - Oluwoo pariwo sita


Oluwo tiluu Iwo nipinlẹ Osun, Oba Abdulrosheed Adewale Akanbi sọrọ, o ni ki awọn eeyan dẹkun gbigbe iroyin ẹlẹjẹ kaakiri ori ayelujara nipa ikọlu awọn agbesunmọmi loju ọna Iwo si Osogbo.

Ọba Akanbi sọ pe ko si agbegbe kan ti awọn agbesunmọmi tabi awọn agbebọn ti ṣe ikọlu, ati pe ayederu iroyin lati ko ibẹrubojo sọkan awọn eeyan lasan ni.

Kabiyesi naa to jẹ olori ọba alaye niluu Iwo jẹ ko di mimọ pe bi ẹnikẹni ba ni ẹri aridaju nipa ibi ti awọn agbesunmọmi ti ṣe ikọlu naa, ki wọn mu jade

O ni eto aabo to f'ẹsẹ mulẹ daadaa wa niluu Iwo, paapaa ipinlẹ Osun, to si rọ awọn araalu lati jẹ ẹni to n sọ otitọ, dipo ki wọn maa gbe iroyin ẹlẹjẹ kaakiri.

"Iroyin wi pe awọn bandiiti ṣe ikọlu loju ọna Iwo si Osogbo ni ana kii ṣe otitọ. Iroyin ẹlẹjẹ ti wọn wunjọ lati bu ẹnu atẹ lu oju ọna naa. Ipinlẹ Osun wa ni alaafia," Oluwo sọ bẹẹ.

"Iṣọkan to wa nipinlẹ Osun duro digbi. Ipinlẹ Osun lo si ni ifọkanbalẹ julọ. A ko gbọdọ gba iroyin ẹlẹjẹ laaye lati maa fo kiri. Ko si ohun to jọ wi pe awọn bandiiti ṣe ikọlu loju ọna Iwo si Osogbo ni ana.

"Mo pe ẹnikẹni to ba ni ẹri lori ikọlu naa lati mu jade. Ẹ f'ọkan balẹ wi pe Iwo wa labẹ aabo labẹ iṣakoso mi. Bi ikọlu kankan ba waye, mo maa debẹ funra mi lati daabo bo awọn eeyan mi," kabiyesi sọ siwaju.

Bakan naa lo rọ araalu nipinlẹ Osun lati maa wa lojufo, ki wọn si fọwọsowọpọ pẹlu awọn agbofinro ti wọn n daabo bo ẹmi ati dukia araalu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI