Muhammad atawọn ọrẹ ẹ, to n fi ayederu tikẹẹti lu jibiti ni Sagamu ha - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, November 22, 2025

Muhammad atawọn ọrẹ ẹ, to n fi ayederu tikẹẹti lu jibiti ni Sagamu ha


Pakopako ni awọn mẹrin kan n wo ni kete tọwọ palaba wọn segi niluu Sagamu, nibi ti wọn ti n fi ayederu tikẹẹti ọkada lu awọn eeyan ni jibiti.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ọlọpaa, Ọmọlọla Odutọla fi ranṣẹ si AWIKONKO, o ni agbegbe abẹ afara Sabo to wa niluu Sagamu, ipinlẹ Ogun, lọwọ ti tẹ awọn mẹrẹẹrin.

Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye fun wa, Odutọla sọ pe ni nnkan bi agogo mẹjọ owurọ, Ọjọbọ, ọsẹ yii, iyẹn ogunjọ, oṣu Kọkanla, ọdun 2025 ni ọwọ tẹ awọn mẹrẹẹrin naa.

Inidana Muhammad, ẹni aadọta ọdun; Ali-Asan Makun Muhammad, ẹni ogoji ọdun; Ahmed Isa, ẹni ọgbọn ọdun ati Saliu Isa, toun jẹ ẹni ọdun mẹtalelogun lawọn mẹrẹẹrin ti Odutọla sọ pe ọwọ tẹ.

O sọ pe ṣadede lawọn ọlọpaa ẹkun Sakura gba ipe pajawiri wi pe awọn kan n fi ayederu tikẹẹti ẹgbẹ ACOMORAN lu awọn ọlọkada ati oni maruwa ni jibiti labẹ afara Sabo, to si loju ẹsẹ ni wọn ti gbera lọ sibẹ.

Siwaju sii lo ni yatọ si awọn ọlọkada ti wọn n lo gbajuẹ fun, wọn tun n gba owo aitọ lọwọ awọn ọlọja to wa nitosi, awọn to ni wọn ko da nnkan mọ.

''Iwadii fidi rẹ mulẹ pe ẹnikan to n jẹ Yinusa to n gbe lagbegbe Sabo, ẹni to ti na papa bora naa, lo ṣe ọpọ ayederu tikẹẹti naa fun wọn lati fi lu jibiti,'' Odutọla ṣalaye.

O lawọn mẹrẹẹrin ti wa ni ẹka ileeṣẹ wọn to n ri sọrọ iwadii ọdaran, nibi ti wọn yoo ti ṣewadii wọn daadaa, ko to di pe wọn foju ba ile-ẹjọ.

Ni bayii, Lanre Ogunlowo to jẹ ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti wa jẹ ko di mimọ pe ko si afurasi ọdaran tọwọ ba tẹ lasiko yii, ti ko nii foju ba ile-ẹjọ lati gba idajọ to tọ sii, ko si jiya rẹ labẹ ofin.

O loun ko nii fọwọ yẹpẹrẹ mu iwa jibiti tabi ilọnilọwọgba lawujọ rara, nitori pe ipinlẹ naa gbọdọ mọ daadaa, ti ifọkanbalẹ si gbọdọ wa fawọn araalu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI