![]() |
| Dokita Folakemi Animashaun |
Ijọba ipinlẹ Eko labẹ iṣakoso Gomina Babajide Sanwo-Olu ti sọ pe ẹgbẹrun lọna ọgọjọ ni iye awọn to n gbe pẹlu arun kogboogun ti HIV nipinlẹ naa lasiko yii.
Ajọ to n ri sọrọ idaabo bo arun AIDS, iyẹn Lagos State AIDS Control Agency ni fi ikede naa sita l'Ọjọbọ, ọsẹ yii, nibi ipade awọn akọroyin ti wọn pe.
Nigba to n fi ikede naa sita lagbegbe Alausa, Ikeja, alakoso agba fun ajọ LSACA, Dokita Folakemi Animashaun, sọ ọ di mimọ pe iye akọsilẹ ti awọn ṣe laaarin oṣu Kinni si oṣu Kẹsan, ọdun 2025 ni wọn fi sita naa.
“Laaarin o'su Kinni si oṣu kẹsan, ọdun 2025, ijọba ipinlẹ Eko ti ṣe akọsilẹ ẹgbẹrun lọna ọgọjọ (160,000) araalu ti wọn n gbe pẹlu arun HIV, to si jẹ pe awọn 147,466 ni wọn n gba itọju antiretroviral lọwọ,” Animashaun sọ ninu ọrọ rẹ.
Bakan naa lo tun gbe oṣuba kare fun Gomina Babajide Sanwo-Olu, to si ṣalaye pe iranwọ ti gomina n ṣe, lo n ṣe igbelarugẹ fun eto ilera kaakiri ipinlẹ naa.

No comments:
Post a Comment