Ile-ẹjọ giga tipinlẹ Oyo to wa niluu Ibadan ti ni ki wọn lọ yẹgi fun awọn ọdaran marun-un kan ti wọn lọwọ ninu awakọ awakọ taisi kan, Akeem Shittu.
Segun Taiwo, ẹni ọdun mẹrindinlogoji; Kehinde Ademola, ẹni ọdun mẹrindinlaadọta; Yahaya Adeniyi, ẹni ọdun marundinlaadọta; Chinonso Samson, ẹni ọdun mọkanlelogoji, ati Opadotun Michael, toun jẹ ẹni ọdun mejilelọgbọn.
Ẹsun meji ọtọọtọ to nii ṣe pẹlu igbimọ papọ ati ipaniyan ni ileeṣẹ ọlọpaa fi kan wọn, ti ile-ẹjọ ti paṣẹ pe wọn jẹbi, pẹlu idajọ iku.
Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Onidajọ Oyeyemi Ajayi ṣalaye pe awọn ẹri toun ri gba, eyi to tako awọn maraarun lo fidi mulẹ pe ogbologbo ọdaran ni wọn jẹ, ti wọn ko si le fọwọ bo o.
Ọkọọkan ninu wọn ni ile-ẹjọ paṣẹ pe ki wọn lọ fi ẹwọn ogun ọdun gbara lori ẹsun igbimọ lati paayan, nigba ti ile-ẹjọ paṣẹ pe ki wọn lọ yẹgi fun wọn lori ẹsun keji.
Ṣaaju asiko yii, agbefọba to foju awọn maraarun han niwaju ile-ẹjọ, Arabinrin K. K. Oloso sọ fun ile-ẹjọ pe ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 ni iṣẹlẹ naa waye ni nnkan bi agogo mẹjọ aabọ, lagbegbe Elepe, loju ọna Arulogun, Ọjọọ niluu Ibadan.
Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, o ni Shittu ti ṣeeṣi fi ọkọ rẹ gba ọkada kan to gbe eeyan meji, leyi to di awuyewuye, ti wọn si lọ si teṣan ọlọpaa lati yanju rẹ.
Nigba ti wọn fẹẹ kuro nibẹ, ni wọn bẹrẹ sii lu wi pe ko le lọ, ti wọn lu lala-jasihoho. Nibi ti wọn ti n lu, lo ti raaye salọ, ṣugbọn ti wọn tun sare tẹle e lẹyin, ko to di pe wọn ṣaa pa.
Taisi rẹ ni wọn pada ri niwaju ṣọọbu ọkan lara awọn ọdaran naa.
Oloso sọ pe ẹsun naa lo tako abala 316, 319, ati 324 ninu iwe ofin ọdaran tipinlẹ Oyo, tọdun 2000.

No comments:
Post a Comment