Epe rabandẹ-rabandẹ lawọn ara agbegbe Fibigbade to wa niluu Agọ-Iwoye n gbe iyale ile kan to bimọ tan, to si lọ ju ọmọ naa sori akitan.
‘Iru kileyi’, lọrọ to n jade lẹnu pupọ awọn abiyamọ to ri ọmọ tuntun naa lori akitan, to n sunkun.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, aarọ kutu ọjọ Ẹti, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2025 ni wọn ṣalabapade ọmọ naa.
Iroyin ilẹ Ijẹbu kan ti wọn pe Ijebu Rewa lori Facebook lo fi ikede naa sita.
"Pẹlu ibanujẹ ọkan, laarọ kutu oni, ohun ti awọn eeyan n gbadura si Ọlọrun fun, ti wọn n lọ si ori oke fun ọpọ ọdun nitori rẹ, ni wọn gbe ju sori akitan lagbegbe Fibigbade niluu Ago Iwoye lonii, ọjọ Ẹti, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2025," Ijebu Rewa kọ ọ bẹẹ.
"Ẹlẹyinju aanu kan to n kọja lọ, lo ṣakiyesi ohun ọmọ tuntun, to si tọpinpin titi to fi ṣawari rẹ. Loju ẹsẹ lo ti ke gbajare si Oloritun agbegbe naa."
Ijebu Rewa fidi rẹ mulẹ pe wọn ti fi iṣẹlẹ ọhun to ileeṣẹ ọlọpaa Abobi leti, ti si ni ọlọpaa kan to n jẹ Stella lo lewaju bi wọn ṣe gbe ọmọ naa lọ sile iwosan alabọde ti Oke Odo lati tọju rẹ.
Bakan naa la gbọ pe kete ti alaga kansu ijọba ibilẹ Ariwa Ijẹbu, Ọnarebu Bolaji Odusanya ti gbọ nipa iṣẹlẹ naa lo ti sare debẹ, to si loun yoo gbe gbogbo bukata lati tọju ọmọ naa, ko to di pe awọn mọ igbesẹ to kan.
No comments:
Post a Comment