Ileeṣẹ Lafarge kọ ile-ẹkọ alakọbẹrẹ lọna igbalode fawọn araalu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, November 28, 2025

Ileeṣẹ Lafarge kọ ile-ẹkọ alakọbẹrẹ lọna igbalode fawọn araalu


Lojuna lati ṣagbelarugẹ fun eto ẹkọ ati ojuṣe iranlọwọ to yẹ labẹ ofin, eyi ti oloyinbo n pe ni Corporate Social Responsibility (CSR), ileeṣẹ Lafarge Africa to n ṣe ojulowo simẹnti nilẹ Afrika, ti ṣe atunkọ ile-ẹkọ alakọbẹrẹ kan niluu Ewekoro, ipinlẹ Ogun.

Ile-ẹkọ alakọbẹrẹ naa ti wọn pe ni Christian Pelamourges Memorial Baptist Day Nursery and Primary School, to wa lagbegbe Agbesi, Ewekoro ni ileeṣẹ naa ṣe atunkọ rẹ.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni ile-ẹkọ naa ti dẹnukọlẹ patapata, ti ko si ba ti igbalode mu, koda, ti wọn lo tun lewu fun ọjọ iwaju awọn ogowẹrẹ nipinlẹ naa.

Ninu atẹjade ti alakoso agba lẹka eto ikansira-ẹni nileeṣẹ naa, Arabinrin Ginikanwa Frank-Durugbor fi ranṣẹ si AWIKONKO l’Ọjọbọ, o ni ọna igbalode ti yoo mu ki eto ẹkọ rọrun fun akẹkọọ ati olukọ ni wọn gba ṣatunkọ ile-ẹkọ naa.

Frank-Durugbor ni awọn kọ kilaasi tuntun,wọn tun ṣe orule to jọju, to fi mọ ọfiisi awọn oṣiṣẹ ati kikọ ṣalanga igbalode ati omi ẹrọ igbalode, fun irọrun awọn eeyan.

Bakan naa lo ni yara ikawe ati, aga ati tabili tuntun, to fi mọ gbogbo ohun ti ile-ẹkọ, paapaa akẹkọọ ati olukọ nilo lati mu ki iṣẹ rọrun ni wọn ṣe sibẹ fun wọn.

Nigba to n sọrọ ninu atẹjade naa, alakoso agba ileeṣẹ naa, Lolu Alade-Akinyẹmi sọ pe lara awọn agbekalẹ ileeṣẹ naa lati gbajumọ ọrọ eto ẹkọ ati awọn ohun ti yoo mu idagbasoke ba agbegbe ati igberiko.

“Ni ileeṣẹ Lafarge Africa, a nigbagbọ pe eto ẹkọ to ye kooro jẹ ohun elo lati fi ṣe igbarugẹ fun ọjọ ọla awọn ọmọde. Nipasẹ irufẹ awọn iṣẹ akanṣe bii ile-ẹkọ Christian Pelamourges Memorial Baptist Day Nursery and Primary School, to wa ni Agbesi, kii ṣe pe a n ṣagbelarugẹ fun ile kikọ nikan, bi ko ṣe pe a tun n ko ipa nigbesi aye awọn ọkan tuntun ti yoo gbe orileede yii soke nipa ẹkọ gidi,” Alade Akinyẹmi sọ bẹẹ.

“Ohun ti a ṣe yii lo ṣafihan ifarajin wa nipa igbelarugẹ si iṣẹ ilu, paapaa agbegbe to gba wa tọwọ-tẹsẹ, lati rii daju pe a ko ya ọmọ kankan sọtọ.”

Nigba toun naa n sọrọ, Kọmiṣanna feto ẹkọ nipinlẹ Ogun, Ọjọgbọn Abayọmi Arigbabu sọ pe iṣẹ akanṣe naa ṣe deedee, to si lọ ni ibamu pẹlu idagbasoke eto ẹkọ lagbaye.

Bẹẹ lo gbe oṣuba kare fun awọn alakoso naa, lori ọna ti wọn n gba ṣe iranwọ fun eto ẹkọ nipinlẹ Ogun, to si ni o lọ ni ibamu pẹlu afojusun ijọba labẹ iṣakoso Gomina Dapọ Abiọdun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI