Ijọba Kwara gbe anfaani idanilẹkọọ nipa imọ ẹrọ AI kalẹ fawọn ọdọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, November 6, 2025

Ijọba Kwara gbe anfaani idanilẹkọọ nipa imọ ẹrọ AI kalẹ fawọn ọdọ


Bi imọ ẹrọ abaniṣiṣẹ agbelẹrọ ti awọn oyinbo n pe ni Artificial Inteligence (AI) ṣe n dagba sii ni gbogbo igba kaakiri agbaye, ijọba ipinlẹ Kwara ti fidi rẹ mulẹ pe ohun ti gbe anfaani idanilẹkọọ kalẹ fawọn ọdọ lati mọ bi wọn yoo ṣe le maa ṣamulo rẹ, fun idagbasoke.

Idanilẹkọọ ọhun ni wọn pe ni 'Kwara AI Summit 2025', eyi ti yoo waye fun ọjọ meji gbako ni gbọngan Ilorin Innovation Hub, bẹrẹ lati agogo mẹjọ aarọ.

Ọjọ kẹtadinlọgbọn si ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 2025 ni idanilẹkọ ọhun yoo waye, nibi ti awọn ọjọgbọn lẹka eto imọ ẹrọ yoo ti maa ṣagbatẹru idanilẹkọọ.

Ni bayii, ijọba ti wa ṣi oju opo iforukọsilẹ fun gbogbo awọn to ba nifẹẹ lati kopa ninu anfaani naa.

Fun iforukọsilẹ: https://www.kwara.ai/

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI