Oni, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2025 lo pe ọjọ mẹsan geerege ti wọn ti n wa obinrin ti ẹ n wo aworan rẹ yii.
Bukola Grace Ojaleye ni orukọ ẹ, oṣiṣẹ eleto ilera nile iwosan alabọde tijọba ibilẹ Ijebu-Ode ni wọn pe e.
Ninu atẹjade ti ọkunrin kan to pe orukọ ara rẹ ni Sanitarian Akinola Oluwarantimi fi soju opo Facebook rẹ, o nnkan bi agogo mẹta ọsan ọjọ naa ni Bukola kuro niluu Abeokuta, to si dagbere pe oun n lọ siluu Ijẹbu-Ode.
Latigba naa lo sọ pe wọn ko ti gburo Bukola mọ, koda to ni ẹrọ ibanisọrọ rẹ ko lọ rara.
O wa rọ awọn eeyan lati ṣe iranwọ lati wa Bukọla nibikibi to ba wa, bẹẹ lo fi nọmba ẹrọ ibanisọrọ 08151627015 to jẹ ti Arabinrin Oseni sita lati pe, bi wọn ba kofiri rẹ.
No comments:
Post a Comment