Ọrọ buruku toun tẹrin nigba ti awọn afurasi ọdaran mẹta kan sọ niwaju ile ẹjọ Majisireeti to wa ladugbo Iṣabọ niluu Abẹokuta wi pe awọn ko jẹbi ẹsun ti ileeṣẹ ọlọpaa fi kan awọn.
Ẹrọ amunawa jẹnẹretọ ni wọn lawọn mẹtẹẹta jigbe lọjọ Abamẹta tii ṣe Satide to kọja lọhun.
Sọdiq Fasasi, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, ti wọn lo n ṣiṣẹ ọlọdẹ ninu ọgba ileeṣẹ iroyin News Agency of Nigeria, iyẹn NAN, ẹka tipinlẹ Ogun to wa niluu Abẹokuta, ni wọn loun pẹlu awọn ọrẹ rẹ meji jọ gbimọ papọ lati ji jẹnẹretọ ọhun gbe.
Ẹrọ amunawa Perkins naa ti wọn ni agbara rẹ to 17KVA ni owo rẹ ko din ni miliọnu meji aabọ naira.
Deedee agogo mẹta kọja iṣẹju mejidinlogun ni wọn sọ pe Fasasi ati awọn ọrẹ rẹ naa, Lukmon Faruq, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn ati Taiwo Adeleke, toun jẹ ọmọ ọdun mọkandinlogun ji jẹnẹretọ ọhun gbe.
Ẹsun mẹta ọtọọtọ to nii ṣe pelu igbimọ papọ, biba dukia jẹ ati ole jija ni wọn fi kan wọn niwaju Onidajọ A.K Araba, l'Ọjọbọ, ọsẹ to kọja.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe niṣe ni Fasasi ranṣẹ pe awọn ọrẹ rẹ meji yii lati gbe mọto ti wọn yoo fi ji jẹnẹretọ ọhun gbe wa ba oun.
Agbefọba Lawrence Olu-Balogun to foju wọn ba ile-ẹjọ ṣalaye pe nibi ti wọn ti n gbe jẹnẹretọ naa lawọn ara adugbo ti kofiri wọn, ti wọn si pariwo ole le wọn lori.
“Awọn ara adugbo lo ta awọn ọlọpaa kogberegbe ti SWAT lolobo, ti wọn fi sare debẹ lati ko wọn. Nigba ti wọn n f'ọrọ wa wọn lẹnu wo, ko si eyi to le sọ pato ibi ti wọn n gbe jẹnẹretọ naa lọ, idi ree ti wọn fi mu wọn.”
Olu-Balogun wa jẹ ko di mimọ pe ẹsun naa lo tako abala 516, 451, 383 ati 390, ninu iwe ofin ọdaran tipinlẹ Ogun ti ọdun 2006.
Nigba to sọrọ, Onidajọ Arabinrin A.K. Araba, wa paṣẹ pe ki wọn gba beeli ẹnikọọkan pẹlu idaji miliọnu naira, ati oniduuro kọọkan to n gbe layika ile ẹjọ.
O wa sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kọkanla, oṣu Kọkanla, ọdun 2025. Bẹẹ lo ni ki wọn wa lọgba ẹwọn Ọba titi wọn yoo fi ri ọrọ beeli naa yanju.
No comments:
Post a Comment