Wọn ti da alaga kansu ti wọn da duro pada sẹnu iṣẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, November 2, 2025

Wọn ti da alaga kansu ti wọn da duro pada sẹnu iṣẹ

Igbimọ iṣakoso ijọba ibilẹ Ado-Odo Ọta nipinlẹ Ogun ti da alaga kansu ti wọn jawe gbele ẹ fun lọsẹ to kọja pada sẹnu iṣẹ rẹ.

Alaaji Wasiu Lawal Adewale ni alaga kansu naa ti wọn ni ko lọ rọkun nile fun oṣu mẹta gbako, lori awọn ẹsun aṣemaṣe ti wọn fi kan an.

Bi wọn ṣe pe ọkunrin naa pada, ko ṣẹyin bi wọn ṣe sọ pe awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC lo da si ọrọ naa, ti wọn si yanju rẹ.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Ọjọru tii ṣe Wẹside ọsẹ to kọja lawọn igbimọ naa gbe aṣẹ yii kalẹ, ti gbogbo awọn aṣoju si tọwọ bọwe lati faramọ ọn.

Ṣugbọn bi iroyin ọhun ṣe jade sita, lawọn eeyan ti bẹrẹ sii sọ oriṣiriṣi ọrọ nipa ohun to ṣokunfa idaduro naa, eyi to fa bi awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu APC ti dide lati da sii.

Nigba to n kede, alaga igbimọ naa, Ọnarebu Gbadamọsi Mutairu Akanji sọ pe bi wọn ṣe da alaga kansu naa pada ko ṣẹyin bi irẹpọ ati iṣọkan ṣe ti pada laaarin awọn tọrọ naa kan.

Ninu ohun ti a gbọ, wọn sọ pe ṣe ni alaga naa n da ijọba ṣe, ti kii sii fi ohun to n lọ han fawọn ti wọn jọ n ṣakoso, eyi ti wọn lo lodi si ilana ati ofin.

Lara awọn to lewaju atunṣe naa ni igbakeji gomina, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ-Oyedele; Ọnarebu Tunji Akinosi to n ṣoju ẹkun Ado-Odo Ọta nile igbimọ aṣoju-ṣofin l'Abuja; Kọmiṣanna f'ọrọ eto aṣa ati irin-ajo afẹ, Ọnarebu Ṣẹsan Fagbayi, ati Oloye Jide Ojuko

Awọn miran ni Oloye Aiyedọgbọn; Ọnarebu Lai Taiwo; Ọnarebu Kazeem Salakọ, to fi mọ alaga APC, Ọnarebu JJ Akẹran.

“Awọn oloye ati agbaagba ti a bọwọ fun yii ni wọn ba wa da si ọrọ to wa nilẹ lati le jẹ ki asọyepọ wa laarin ijọba ibilẹ wa,” Ọnarebu Akanji sọ bẹẹ.

Bakan ni wọn jẹ ko di mimọ pe Alaaji Adewale ti gba lati ṣe ohun ti igbimọ naa fẹ, ki ilọsiwaju ati ajọṣepọ to dan mọnran le wa lati mu itẹsiwaju ba ijọba ibilẹ Ado-Odo Ọta.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI