Godonu lu iyawo rẹ pa, lo ba tun fẹẹ lo sinku ẹ ni bonkẹlẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, November 22, 2025

Godonu lu iyawo rẹ pa, lo ba tun fẹẹ lo sinku ẹ ni bonkẹlẹ


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ baale kan, Godonu Lowe ti wọn fura si pe o lu iyawo rẹ pa, to si fẹ lọ ju oku naa danu, ki aṣiri ma ba a tu sita.

Okete Godonu ko raaye boru mọ awọn ọlọpaa lọwọ, lasiko to fẹẹ na papa bora pẹlu oku iyawo rẹ to fẹ lọ ju sọnu sinu igbo.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ṣe fidi rẹ mulẹ, Ọmọlọla Odutọla to jẹ agbẹnusọ wọn ṣalaye pe Ọjọru, Wẹside, ọsẹ yii lọwọ tẹ Godonu lasiko to n gbe oku obinrin naa lọ.

Odutọla jẹ ko di mimọ pe ori ọkada ni Godonu wa nigba ti awọn ọlọpaa daa duro, lati ṣayẹwo rẹ.

Nibi ti wọn ti n f'ọrọ wa a lẹnu wo lọwọ ni wọn ti fura si apo ṣaka kan ti ọkunrin naa sọ kọ si ẹyin ọkada rẹ.

"Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun tun ṣiṣẹ takuntakun to fidi iṣẹ iwadii mulẹ nipa dida awọn eeyan duro lati ṣe iwadii wọn, ninu eyi ti wọn ti rọwọ to afurasi apaaalyan kan niluu Ilaro," Odutọla sọ eyi ninu atẹjade to fi sita.

"Ni nnkan bi agogo kan kọja iṣẹju marun-un, Ọjọru, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2025, awọn ọlọpaa ẹkun Ilaro gba olobo kan pe ọkunrin kan ti wọn fura si, Godonu Lowe, to n gbe labule Omolende nitosi Idogo, n gbe oku obinrin kan ti wọn ko mọ lọ, lori ọkada, pẹlu erongba lati gbe e kuro niluu.'' Odutọla ṣalaye

O ni lẹsẹkẹsẹ ti wọn ti ṣakiyesi baagi naa ni wọn ti sọ pe ko tu, lati le jẹ ki wọn ri ohun to wa ninu ẹ, ṣugbọn ti wọn sọ pe ko tete fẹẹ dahun.

Nigba to rii pe wọn ko mu ọrọ naa ni awada pẹlu ẹ, lo jẹ ko sare tu, to si jẹ kayeefi pe oku obinrin kan lo wa ninu rẹ.

Nibi ti wọn ti n fọrọ wa a lẹnu wo, lo ti pada jẹwọ pe iyawo oun ni.

Ayẹwo ti awọn ọlọpaa ṣe lara oku naa, ni wọn ti ṣakiyesi oniruuru ọgbẹ ati apa lara rẹ, to si jẹ ki wọn nigbagbọ pe niṣe lo lu obinrin naa to fi dakẹ.

Yatọ si eyi, wọn tun rii pe ẹjẹ n da lara oku naa, koda, ti wọn tun ri ada to fi lu iyawo rẹ pa ninu ọkada naa.

Odutọla ti wa jẹ ko ye wa pe afurasi naa ti wa lahaamọ ni olu ileeṣẹ wọn to wa ni Elewran niluu Abeokuta, nibi ti wọn ti n fọrọ wa a lẹnu wo.

Bẹẹ lo sọ pe wọn tun ti gbe oku naa lọ si mọṣuari ile iwosan ijọba to wa ni Ilaro, nibi ti wọn yoo ti ṣayẹwo to tọ fun un.

O wa sọ pe ọga awọn, Lanre Ogunlowo ti paṣẹ pe ki iwadii ijinlẹ waye, ko to di pe wọn lọ foju rẹ ba ile-ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI