Ijamba ina gaasi fọpọ ẹmi ṣofo n'Ibadan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, November 22, 2025

Ijamba ina gaasi fọpọ ẹmi ṣofo n'Ibadan


Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni a ko tii le fidi awọn to ba ijamba ina gaasi to waye lagbegbe Bioku-Alaadun nigboro ilu Ibadan, ipinlẹ Oyo lọ lọjọ Ẹti to kọja yii, ṣibẹ, a gbọ pe ẹmi ẹmi lo ṣofo danu.

Ariwo ikunlẹ abiyamọ lo gba ẹnu awọn eeyan lagbegbe ijọba ibilẹ Ona Ara naa nigba ti ina gaasi ṣẹyọ lalẹ ọjọ furaide, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2025.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ, wọn ni tanka agbe gaasi lo gbina lojiji lasiko to n ja gaasi to gbe sile gaasi kan lagbegbe naa.

Ọpọ awọn to wa nitosi ṣọọbu gaasi ọhun, to fi mọ ẹni to nii, lo ba ijamba ina naa lọ loju ẹsẹ.

Alakoso agba ileeṣẹ panapana nipinlẹ Oyo, Yemi Akinyinka nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn akọroyin, o ni ibanujẹ nla nijamba naa jẹ, ati pe igbesẹ n lọ lati dẹkun ina naa.

O jẹ ko di mimọ pe awọn oṣiṣẹ wọn ti wa nibẹ, lati pa ina ọhun.

Akinyinka fidi rẹ mulẹ pe “Awọn oṣiṣẹ wa, wa nibẹ. Bẹẹni, otitọ ni ijamba naa waye. Wọn n ra gaasi lọwọ ni, ko to di pe ibugbamnu waye. A ṣi n ṣagbeyẹwo iye awọn to fara kaaṣa lọwọ.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI