Ọpẹ o! Ijọba Kwara kede ayipada ati ilana tuntun lẹka eto ẹkọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, November 18, 2025

Ọpẹ o! Ijọba Kwara kede ayipada ati ilana tuntun lẹka eto ẹkọ


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti kede awọn ayipada ati ilana tuntun lẹka eto ẹkọ.

Awọn ayipada ati ilana tuntun naa, leyi ti yoo jẹ ki awọn akẹkọọ tubọ dantọ lẹnu ẹkọ wọn.

Lara awọn ayipada tuntun naa ni ti ilana tuntun ti yoo fa ijiroro laaarin awọn akẹkọọ ati olukọ.

Eyiu ni yoo jẹ ki awọn akẹkọọ kọ nipa ikora-ẹni nijanu, ninu iwa ọmọluwabi ati iwa to dara lawujọ.

Kọmiṣanna f'ọrọ eto ẹkọ, Lawal Olohungbebe lo sọ eyi di mimọ nibi ipade awọn akọroyin to maa n waye ni igba mẹrin ninu ọdun.

Kọmiṣanna ṣalaye pe ohun to ṣe pataki ni ki awọn akẹkọọ mọ ọna pati ko ara wọn nijanu, ki wọn ma ba a ṣiwa wu.

Bẹẹ lo sọ pe oniruuru iṣẹ akanṣe idagbasoke lo ti n lọ kaaiiri awọn ile-ẹkọ, lati mu ki eto ẹkọ tẹsiwaju, leyi ti yoo ba ti igbalode mu.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI