Igbakeji gomina yoo ṣakoso igbimọ eleto aabo ti Gomina AbdulRazaq gbe kalẹ ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, November 25, 2025

Igbakeji gomina yoo ṣakoso igbimọ eleto aabo ti Gomina AbdulRazaq gbe kalẹ ni Kwara


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti kede igbakeji rẹ, Kayọde Alabi gẹgẹ bi alaga igbimọ eleto aabo ti yoo ṣakoso ọna tuntun lati ṣabojuto ilana eto aabo nipinlẹ Kwara.

Igbimọ naa la gbọ pe wọn yoo jokoo ipade papọ pẹlu awọn agbaagba kaakiri ipinlẹ naa, bii ọba alaye, baalẹ, alaga agbegbe ati bẹẹbẹẹlọ.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin gomina, Rafiu Ajakaye fi sita loni, ọjọ Iṣẹgun, AbdulRazaq sọ pe igbimọ naa yoo ṣepade pẹlu awọn eekan lawujọ lati ri sọrọ ọna abayọ lati koju eto aabo lawọn agbegbe ati igberiko.

Bakan naa lawọn igbimọ ọhun yoo tun ri si ọna ati eto aabo gba mẹhẹ, lojuna lati koju iṣoro to n de ba ọrọ eto aabo kaakiri ipinlẹ naa.

Arabirin Olufunke Mercy Shittu ti ileeṣẹ olori awọn oṣiṣẹ ijọba ni yoo ṣe akọwe igbimọ naa.

Lara awọn ọmọ igbimọ naa tun ni oludamọran pataki lori eto aabo ni Kwara, Brigadier General Saliu Tunde Bello; Kọmiṣanna feto ijọba ibilẹ ati oye jijẹ, Abdullahi Bata; Alaaji Muhyideen Aliu; Alaaji Moshood Gobir; to fi mọ alaga ijọba ibilẹ mẹta lati ẹkun eto idibo mẹta to wa nipinlẹ naa.

“Igbimọ naa yoo gbe iwadii wọn kalẹ siwaju gomina laaarin ọsẹ mẹrin lati mọ ọna abayọ. Eyi si ni yoo tubọ jẹ ki eto aabo ni idagbasoke lawọn ijọba ibilẹ kaakiri,” Ajakaye sọ ninu atẹjade naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI