Ijọba Kwara tun fi ẹgbẹrun meji aabọ aṣọ aabọ ori omi ta awọn araalu lọrẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, November 18, 2025

Ijọba Kwara tun fi ẹgbẹrun meji aabọ aṣọ aabọ ori omi ta awọn araalu lọrẹ


Lati le jẹ ki aabo wa fun gbogbo awọn arinrin-ajo ori omi, ijọba ipinlẹ Kwara ti fi awọn aṣọ aabo, ti a mọ si 'life jacket' ta awọn araalu lọrẹ, paapaa awọn ileeṣẹ to n ri sọrọ irin-ajo ori omi.

Ẹgbẹrun meji aabọ awọn aṣọ aabo naa ni ijọba fi ta wọn lọrẹ, leyi to mu ki ijọba kede pe ko si irin-ajo ori omi lai si aṣọ aabo.

Ẹnikẹni ti ko ba ti wọ aṣọ aabo, ko le ni anfaani lati rin irin-ajo ori omi, gẹgẹ bi ijọba ṣe kede rẹ.

Gbogbo awọn ileeṣẹ to n ri sọrọ irin-ajo ori omi to wa lawọn ijọba ibilẹ bii Moro, Kaiama, Patigi, Edu ati Baruten nijọba pin awọn aṣọ aabo naa si.

Nigba to n kede lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq sọ pe aabo ẹmi ati dukia jẹ ijọba oun logun pupọ, toun si gbọdọ maa wa ọna lati dẹkun ijamba to le f'ẹmi awọn eeyan ṣofo.

AbdulRazaq jẹ ko di mimọ pe oniruuru ijamba ori omi lo ti ṣẹlẹ, to si ti f'ẹmi ọpọ ṣofo, ṣugbọn to lo pọn dandan fun ijọba lati wa ọna abayọ ti yoo dẹkun irufẹ ijamba bẹẹ.




No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI