Igbakeji aarẹ ilẹ Naijiria nigba kan ri, Alaaji Atiku Abubakar ti sọ pe ko sẹni to le da ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC duro lati kopa ninu eto idibọ ọdun 2027.
Atiku ni gbogbo igbaradi ni ẹgbẹ naa ti n ṣe bayii, lati rii pe wọn ko ipa to jọju ninu eto idibo ọdun 2027, to si loun nigbagbọ pe wọn yoo jawe olubori.
Oludije sipo aarẹ Naijiria lọdun to kọja labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP lo sọrọ naa lasiko to n forukọ silẹ gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ oṣelu ADC niluu Yola, ipinlẹ Adamawa l'Ọjọbọ, ọsẹ yii ṣalaye loju opo 'X' rẹ lonii, ọjọ Ẹti.
Nigba to n fi aworan ara rẹ nibi to ti gba kaadi ojulowo ọmọ ẹgbẹ naa, o ni ere tuntun ti bẹrẹ bayii.
Bakan naa lo sọ pe awọn ti bẹrẹ ipolongo kaakiri ilẹ Naijiria, lati le jẹ ki araalu mọ bi idibo yoo ṣe lọ lọdun 2027.
“Ni ana, ọkọ reluwe ADC duro niluu Jalingo lati ṣafihan ileeṣẹ ẹgbẹ naa nipinlẹ Taraba fun apapọ ẹgbẹ naa. Ko sẹni to le da ADC duro; o n bọ loju ọna rẹ,” Atiku kọ ọ loju opo 'X' rẹ.

No comments:
Post a Comment