Iyale ile ti ololufẹ ikọkọ rẹ gbe lọ si otẹẹli ku lẹyin ibalopọ gbigbona l'Ondo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, November 28, 2025

Iyale ile ti ololufẹ ikọkọ rẹ gbe lọ si otẹẹli ku lẹyin ibalopọ gbigbona l'Ondo


Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ṣi n sọ pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori iku obinrin kan to ku si otẹẹli, sibẹ, iyalẹnu lọrọ obinrin naa ṣi n jẹ fun ọpọ awọn eeyan.

Obinrin naa la gbọ pe oun pẹlu ololufẹ ikọkọ rẹ jọ lọ gbadun ara wọn ni otẹẹli kan to wa ni Ọrẹ, ijọba ibilẹ Odigbo nipinlẹ Ondo, ṣugbọn to pada dakẹ si otẹẹli naa.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni obinrin naa pẹlu ọrẹkunrin ikọkọ rẹ ni wọn jọ wọ otẹẹli ọhun laarọ Ọjọru, ọsẹ yii, ṣugbọn ti wọn sọ pe oku rẹ ni wọn pada ba ninu yara, nigba to di irọlẹ.

Ko sẹni to mọ bi ọkunrin ti wọn jọ wọ otẹẹli naa ṣe rin in, ti wọn si ni kete to ṣakiyesi pe obinrin naa ti dakẹ, lo ti juba ehoro, ki aṣiri ma ba a tu.

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ otẹẹli naa to sọrọ, ṣalaye pe awọn ko le sọ bi ọkunrin naa ṣe poora, ati pe nigba ti awọn yoo fi kofiri obinrin naa, ẹlẹmi ti gba a.

“Awọn mejeeji ni wọn jọ de laaarọ ọjọ naa, ṣugbọn nigba ti oṣiṣẹ kan lọ sinu yara naa lati wo ohun to n lọ, niṣe lo ba oku obinrin naa lori bẹẹdi, wọn ko ri ọkunrin ọhun.

“Oṣiṣẹ naa lo ke gbajare sita, to si mu kawọn to wa nibẹ sare wọlba teṣan ọlọpaa lọ lati fi to wọn leti ni Ore,” ẹni naa sọ bẹẹ.

Gẹgẹ bi wọn tun ṣe sọ siwaju, wọn ni ko si apa kankan ni ara obinrin naa, leyi ti ko ṣafihan boya ija waye laaarin awọn mejeeji, ko to di ọrọ iku.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, agbẹnusọ ọlọpaa, Olayinka Ayanlade sọ l'Ọjọbọ, ọsẹ yii pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lati rọwọ to afurasi to na papa bora.

“Lotitọ ni, iṣẹlẹ naa waye, a ti bẹrẹ iṣẹ iwadii wa, ati pe igbesẹ lati rọwọ to afurasi to na papa bora ti bẹrẹ,” agbẹnusọ ọlọpaa sọ bẹẹ.

Bẹẹ lo ni wọn ti gbe oku obinrin naa lọ si mọṣuari ile iwosan ijọba to wa nitosi, fun iwadii siwaju sii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI